ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sekaráyà 3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sekaráyà

      • Ìran 4: Wọ́n fún àlùfáà àgbà ní aṣọ míì (1-10)

        • Sátánì ta ko Àlùfáà Àgbà Jóṣúà (1)

        • ‘Màá mú ìránṣẹ́ mi tó ń jẹ́ Èéhù wá!’ (8)

Sekaráyà 3:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 5:2; Hag 1:14; Sek 6:11
  • +Job 1:6

Sekaráyà 3:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jud 9
  • +2Kr 6:6; Sek 2:12

Sekaráyà 3:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ̀bi.”

  • *

    Tàbí “aṣọ ìgúnwà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 28:2

Sekaráyà 3:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:6

Sekaráyà 3:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tọ́jú; ṣọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mal 2:7

Sekaráyà 3:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 42:1; 52:13
  • +Ais 11:1; 53:2, 11; Jer 23:5; 33:15; Sek 6:12

Sekaráyà 3:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 50:20

Sekaráyà 3:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 4:25; Ho 2:18; Mik 4:4

Àwọn míì

Sek. 3:1Ẹsr 5:2; Hag 1:14; Sek 6:11
Sek. 3:1Job 1:6
Sek. 3:2Jud 9
Sek. 3:22Kr 6:6; Sek 2:12
Sek. 3:4Ẹk 28:2
Sek. 3:5Ẹk 29:6
Sek. 3:7Mal 2:7
Sek. 3:8Ais 42:1; 52:13
Sek. 3:8Ais 11:1; 53:2, 11; Jer 23:5; 33:15; Sek 6:12
Sek. 3:9Jer 50:20
Sek. 3:101Ọb 4:25; Ho 2:18; Mik 4:4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sekaráyà 3:1-10

Sekaráyà

3 Ó sì fi Jóṣúà + tó jẹ́ àlùfáà àgbà hàn mí, ó dúró níwájú áńgẹ́lì Jèhófà, Sátánì+ sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kó lè ta kò ó. 2 Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún Sátánì pé: “Kí Jèhófà bá ọ wí, ìwọ Sátánì,+ bẹ́ẹ̀ ni, kí Jèhófà, ẹni tó yan Jerúsálẹ́mù+ bá ọ wí! Ṣebí ẹni yìí ni igi tó ń jó tí wọ́n yọ kúrò nínú iná?”

3 Aṣọ ọrùn Jóṣúà dọ̀tí, ó sì dúró níwájú áńgẹ́lì náà. 4 Áńgẹ́lì náà sọ fún àwọn tó dúró níwájú rẹ̀ pé: “Ẹ bọ́ aṣọ ìdọ̀tí tó wà lọ́rùn rẹ̀.” Ó wá sọ fún un pé: “Wò ó, mo ti mú ẹ̀ṣẹ̀* rẹ kúrò, ìwọ yóò sì wọ aṣọ tó mọ́.”*+

5 Torí náà, mo sọ pé: “Ẹ fi láwàní tó mọ́ wé e lórí.”+ Wọ́n fi láwàní náà wé e lórí, wọ́n sì wọ aṣọ fún un; áńgẹ́lì Jèhófà sì dúró nítòsí. 6 Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: 7 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Tí o bá rìn ní àwọn ọ̀nà mi, tí o sì ń ṣe ojúṣe rẹ sí mi, ìwọ yóò di adájọ́ ní ilé mi,+ ìwọ yóò sì máa bójú tó* àwọn àgbàlá mi; èmi yóò sì fún ọ láǹfààní bíi ti àwọn tó dúró síbí.’

8 “‘Àlùfáà Àgbà Jóṣúà, jọ̀ọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ àti àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n jókòó níwájú rẹ, torí àwọn ọkùnrin yìí jẹ́ àmì; wò ó! mò ń mú ìránṣẹ́ mi+ tó ń jẹ́ Èéhù+ bọ̀! 9 Wo òkúta tí mo fi síwájú Jóṣúà! Ojú méje ló wà lára òkúta náà; èmi yóò kọ nǹkan sí ara rẹ̀, èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan ṣoṣo,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.+

10 “‘Ní ọjọ́ yẹn, kálukú yín yóò pe aládùúgbò rẹ̀ pé kó wá sí abẹ́ àjàrà àti abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ òun,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́