ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Sámúẹ́lì

      • Sọ́ọ̀lù ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámónì (1-11)

      • A fìdí ipò ọba Sọ́ọ̀lù múlẹ̀ (12-15)

1 Sámúẹ́lì 11:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú wa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 2:19
  • +Ond 21:8; 1Sa 31:11, 12

1 Sámúẹ́lì 11:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    12/15/1995, ojú ìwé 9-10

1 Sámúẹ́lì 11:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Gíbíà ti Sọ́ọ̀lù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 10:26; 14:2

1 Sámúẹ́lì 11:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 3:9, 10; 6:34; 11:29; 14:5, 6; 1Sa 10:10, 11; 16:13

1 Sámúẹ́lì 11:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “bí ọkùnrin kan.”

1 Sámúẹ́lì 11:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 11:3

1 Sámúẹ́lì 11:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ní nǹkan bí aago méjì òru sí mẹ́fà àárọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 11:1

1 Sámúẹ́lì 11:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 10:26, 27

1 Sámúẹ́lì 11:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 19:22

1 Sámúẹ́lì 11:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 7:15, 16
  • +1Sa 10:17, 24

1 Sámúẹ́lì 11:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 7:11
  • +1Ọb 1:39, 40; 2Ọb 11:12, 14; 1Kr 12:39, 40

Àwọn míì

1 Sám. 11:1Di 2:19
1 Sám. 11:1Ond 21:8; 1Sa 31:11, 12
1 Sám. 11:41Sa 10:26; 14:2
1 Sám. 11:6Ond 3:9, 10; 6:34; 11:29; 14:5, 6; 1Sa 10:10, 11; 16:13
1 Sám. 11:101Sa 11:3
1 Sám. 11:111Sa 11:1
1 Sám. 11:121Sa 10:26, 27
1 Sám. 11:132Sa 19:22
1 Sám. 11:141Sa 7:15, 16
1 Sám. 11:141Sa 10:17, 24
1 Sám. 11:15Le 7:11
1 Sám. 11:151Ọb 1:39, 40; 2Ọb 11:12, 14; 1Kr 12:39, 40
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Sámúẹ́lì 11:1-15

Sámúẹ́lì Kìíní

11 Nígbà náà, Náháṣì ará Ámónì+ wá pàgọ́ ti ìlú Jábéṣì ní Gílíádì. Gbogbo ọkùnrin Jábéṣì+ sì sọ fún Náháṣì pé: “Bá wa dá májẹ̀mú,* a ó sì sìn ọ́.” 2 Náháṣì ará Ámónì fún wọn lésì pé: “Ohun tí mo lè fi bá yín dá májẹ̀mú ni pé: Màá yọ ojú ọ̀tún ẹnì kọ̀ọ̀kan yín jáde kí n lè dójú ti gbogbo Ísírẹ́lì.” 3 Àwọn àgbààgbà ìlú Jábéṣì fún un lésì pé: “Fún wa ní ọjọ́ méje, ká lè rán àwọn òjíṣẹ́ sí gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì. Tí a ò bá wá rí ẹni gbà wá, a ó fi ara wa lé ọ lọ́wọ́.” 4 Nígbà tó yá, àwọn òjíṣẹ́ náà dé Gíbíà+ ìlú Sọ́ọ̀lù,* wọ́n sọ ọ̀rọ̀ náà ní etí àwọn èèyàn, gbogbo àwọn èèyàn náà sì ń sunkún kíkankíkan.

5 Àmọ́ Sọ́ọ̀lù ń da ọ̀wọ́ ẹran bọ̀ láti pápá, ó sì sọ pé: “Kí ló ṣe àwọn èèyàn yìí? Kí ló ń pa wọ́n lẹ́kún?” Torí náà, wọ́n ròyìn ohun tí àwọn ọkùnrin Jábéṣì sọ fún un. 6 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀mí Ọlọ́run fún un lágbára,+ inú sì bí i gidigidi. 7 Torí náà, ó mú akọ màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì fi wọ́n rán àwọn òjíṣẹ́ náà sí gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n sọ pé: “Báyìí ni a máa ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù àti Sámúẹ́lì!” Ìbẹ̀rù Jèhófà sì mú kí àwọn èèyàn náà jáde ní ìṣọ̀kan.* 8 Nígbà náà, ó ka iye wọn ní Bésékì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000), àwọn ọkùnrin Júdà sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000). 9 Ni wọ́n bá sọ fún àwọn òjíṣẹ́ tó wá pé: “Ohun tí ẹ máa sọ fún àwọn èèyàn Jábéṣì ní Gílíádì nìyí, ‘Lọ́la, nígbà tí oòrùn bá mú, a máa gbà yín.’” Àwọn òjíṣẹ́ náà wá lọ sọ fún àwọn ọkùnrin Jábéṣì, inú wọn sì dùn gan-an. 10 Torí náà, àwọn ọkùnrin Jábéṣì sọ fún àwọn ọmọ Ámónì pé: “Lọ́la, a máa fi ara wa lé yín lọ́wọ́, kí ẹ ṣe ohun tó bá wù yín sí wa.”+

11 Ní ọjọ́ kejì, Sọ́ọ̀lù pín àwọn èèyàn náà sí àwùjọ mẹ́ta, wọ́n lọ sí àárín ibùdó náà ní àkókò ìṣọ́ òwúrọ̀,* wọ́n sì ń pa àwọn ọmọ Ámónì+ títí ọ̀sán fi pọ́n. Àwọn tó yè bọ́ fọ́n ká, tó fi jẹ́ pé kò sí méjì lára wọn tí ó wà pa pọ̀. 12 Àwọn èèyàn náà wá sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Àwọn wo ló ń sọ pé, ‘Ṣé Sọ́ọ̀lù ló máa jẹ ọba lé wa lórí?’+ Ẹ fi wọ́n lé wa lọ́wọ́, a ó sì pa wọ́n.” 13 Àmọ́ Sọ́ọ̀lù sọ pé: “A ò gbọ́dọ̀ pa ẹnikẹ́ni lónìí yìí,+ torí pé òní ni Jèhófà gba Ísírẹ́lì sílẹ̀.”

14 Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ wá kí a lọ sí Gílígálì+ láti fìdí ipò ọba náà múlẹ̀.”+ 15 Torí náà, gbogbo àwọn èèyàn náà lọ sí Gílígálì, wọ́n sì fi Sọ́ọ̀lù jẹ ọba níwájú Jèhófà ní Gílígálì. Wọ́n rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níbẹ̀ níwájú Jèhófà,+ Sọ́ọ̀lù àti gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì sì ṣe ayẹyẹ pẹ̀lú ìdùnnú ńlá.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́