ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Hágárì àti Íṣímáẹ́lì (1-16)

Jẹ́nẹ́sísì 16:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:2, 3
  • +Ga 4:25

Jẹ́nẹ́sísì 16:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:1, 3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 5 2017 ojú ìwé 12-13

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2004, ojú ìwé 27

Jẹ́nẹ́sísì 16:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 5 2017 ojú ìwé 13-14

Jẹ́nẹ́sísì 16:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lé àyà rẹ.”

Jẹ́nẹ́sísì 16:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 5 2017 ojú ìwé 13-14

Jẹ́nẹ́sísì 16:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 25:17, 18; Ẹk 15:22

Jẹ́nẹ́sísì 16:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “rẹ ara rẹ sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”

Jẹ́nẹ́sísì 16:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:20; 25:13-16; 1Kr 1:29-31

Jẹ́nẹ́sísì 16:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Ń Gbọ́.”

Jẹ́nẹ́sísì 16:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí oríṣi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó kan tí wọ́n ń pè ní onager lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́, àwọn kan gbà pé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà ni. Ó lè jẹ́ torí pé kì í gbára lé ẹnikẹ́ni.

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “kò ní sí àlàáfíà láàárín òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀.”

Jẹ́nẹ́sísì 16:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 15:3

Jẹ́nẹ́sísì 16:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Kànga Ẹni Tó Wà Láàyè Tó Ń Rí Mi.”

Jẹ́nẹ́sísì 16:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 21:9; Ga 4:22, 24

Àwọn míì

Jẹ́n. 16:1Jẹ 15:2, 3
Jẹ́n. 16:1Ga 4:25
Jẹ́n. 16:2Jẹ 30:1, 3
Jẹ́n. 16:7Jẹ 25:17, 18; Ẹk 15:22
Jẹ́n. 16:10Jẹ 17:20; 25:13-16; 1Kr 1:29-31
Jẹ́n. 16:13Owe 15:3
Jẹ́n. 16:15Jẹ 21:9; Ga 4:22, 24
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 16:1-16

Jẹ́nẹ́sísì

16 Sáráì ìyàwó Ábúrámù kò bí ọmọ kankan+ fún un, àmọ́ ó ní ìránṣẹ́ kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì, Hágárì+ ni orúkọ rẹ̀. 2 Sáráì wá sọ fún Ábúrámù pé: “Jọ̀ọ́, gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ! Jèhófà ò jẹ́ kí n bímọ. Jọ̀ọ́, bá ìránṣẹ́ mi ní àṣepọ̀. Bóyá mo lè ní ọmọ nípasẹ̀ rẹ̀.”+ Ábúrámù sì fetí sí ohun tí Sáráì sọ. 3 Lẹ́yìn tí Ábúrámù ti lo ọdún mẹ́wàá ní ilẹ̀ Kénáánì, Sáráì ìyàwó Ábúrámù mú Hágárì, ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì, ó sì fún Ábúrámù ọkọ rẹ̀ kó fi ṣe aya. 4 Ábúrámù wá bá Hágárì ní àṣepọ̀, ó sì lóyún. Nígbà tó rí i pé òun ti lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fojú àbùkù wo Sáráì ọ̀gá rẹ̀.

5 Torí náà, Sáráì sọ fún Ábúrámù pé: “Ìwọ lo fa ìyà tó ń jẹ mí. Èmi ni mo fa ìránṣẹ́ mi lé ọ lọ́wọ́,* àmọ́ nígbà tó rí i pé òun ti lóyún, ó wá ń fojú àbùkù wò mí. Kí Jèhófà ṣèdájọ́ èmi àti ìwọ.” 6 Ábúrámù wá sọ fún Sáráì pé: “Wò ó! O ní àṣẹ lórí ìránṣẹ́ rẹ. Ohun tí o bá rí i pé ó dáa jù ni kí o ṣe fún un.” Sáráì wá ni ín lára, ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

7 Nígbà tó yá, áńgẹ́lì Jèhófà rí i níbi ìsun omi kan nínú aginjù, ìsun omi tó wà lójú ọ̀nà Ṣúrì.+ 8 Ó sì sọ pé: “Hágárì, ìránṣẹ́ Sáráì, ibo lo ti ń bọ̀, ibo lo sì ń lọ?” Ó fèsì pé: “Mo sá kúrò lọ́dọ̀ Sáráì ọ̀gá mi ni.” 9 Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún un pé: “Pa dà sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ, kí o sì tẹrí ba fún un.”* 10 Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ pé: “Èmi yóò mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ gan-an débi pé wọn ò ní lè kà wọ́n.”+ 11 Áńgẹ́lì Jèhófà fi kún un pé: “O ti lóyún, wàá sì bí ọmọkùnrin kan, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Íṣímáẹ́lì,* torí Jèhófà ti gbọ́ nípa ìyà tó ń jẹ ọ́. 12 Ó máa dà bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó.* Ó máa bá gbogbo èèyàn jà, gbogbo èèyàn á sì bá a jà, òdìkejì gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ ni á máa gbé.”*

13 Ó wá ké pe orúkọ Jèhófà, ẹni tó ń bá a sọ̀rọ̀, ó sì sọ pé: “Ọlọ́run tó ń ríran+ ni ọ́,” torí ó sọ pé: “Ṣé kì í ṣe pé mo ti rí ẹni tó ń rí mi lóòótọ́!” 14 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe kànga náà ní Bia-laháí-róì.* (Ó wà láàárín Kádéṣì àti Bérédì.) 15 Hágárì wá bí ọmọkùnrin kan fún Ábúrámù, Ábúrámù sì pe orúkọ ọmọ tí Hágárì bí fún un ní Íṣímáẹ́lì.+ 16 Ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún (86) ni Ábúrámù nígbà tí Hágárì bí Íṣímáẹ́lì fún un.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́