ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Onídàájọ́ 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àwọn Onídàájọ́

      • Jábínì ọba Kénáánì fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (1-3)

      • Dèbórà wòlíì obìnrin àti Bárákì onídàájọ́ (4-16)

      • Jáẹ́lì pa Sísérà olórí ogun (17-24)

Àwọn Onídàájọ́ 4:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 2:19

Àwọn Onídàájọ́ 4:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Haroṣeti-há-góímù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 2:14; 3:8; 10:7
  • +Ond 4:16

Àwọn Onídàájọ́ 4:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ó.”

  • *

    Ní Héb., “kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 2:18; 3:9; Sm 107:19
  • +Joṣ 17:16; Ond 1:19
  • +Di 28:48

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2017, ojú ìwé 29

Àwọn Onídàájọ́ 4:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:20; 2Ọb 22:14; Lk 2:36; Iṣe 21:8, 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 12

Àwọn Onídàájọ́ 4:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 18:21, 25
  • +Jẹ 28:17, 19

Àwọn Onídàájọ́ 4:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Pín àwọn ọkùnrin rẹ sórí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:32
  • +Joṣ 21:32

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2003, ojú ìwé 28-29

Àwọn Onídàájọ́ 4:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àfonífojì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 18:40; Sm 83:9
  • +Di 20:1

Àwọn Onídàájọ́ 4:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 13

    1/15/2005, ojú ìwé 25

    11/15/2003, ojú ìwé 29

Àwọn Onídàájọ́ 4:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:21, 22; 5:24, 26
  • +Joṣ 20:7, 9; 21:32

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2003, ojú ìwé 29

Àwọn Onídàájọ́ 4:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 5:18

Àwọn Onídàájọ́ 4:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 24:21; Ond 1:16; 1Sa 15:6
  • +Nọ 10:29

Àwọn Onídàájọ́ 4:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:6

Àwọn Onídàájọ́ 4:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe.”

  • *

    Tàbí “àfonífojì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 5:20, 21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2017, ojú ìwé 29

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 14

Àwọn Onídàájọ́ 4:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 14

    12/15/1998, ojú ìwé 11-12

Àwọn Onídàájọ́ 4:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 14:24; Joṣ 10:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 14

    12/15/1998, ojú ìwé 11-12

Àwọn Onídàájọ́ 4:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 14

Àwọn Onídàájọ́ 4:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 5:24
  • +Ond 4:11
  • +Ond 4:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 14

Àwọn Onídàájọ́ 4:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 15

Àwọn Onídàájọ́ 4:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 5:25

Àwọn Onídàájọ́ 4:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:9; 5:26, 27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 15

Àwọn Onídàájọ́ 4:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 15

Àwọn Onídàájọ́ 4:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:32, 33

Àwọn Onídàájọ́ 4:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:25
  • +Di 7:24

Àwọn míì

Oníd. 4:1Ond 2:19
Oníd. 4:2Ond 2:14; 3:8; 10:7
Oníd. 4:2Ond 4:16
Oníd. 4:3Ond 2:18; 3:9; Sm 107:19
Oníd. 4:3Joṣ 17:16; Ond 1:19
Oníd. 4:3Di 28:48
Oníd. 4:4Ẹk 15:20; 2Ọb 22:14; Lk 2:36; Iṣe 21:8, 9
Oníd. 4:5Joṣ 18:21, 25
Oníd. 4:5Jẹ 28:17, 19
Oníd. 4:6Heb 11:32
Oníd. 4:6Joṣ 21:32
Oníd. 4:71Ọb 18:40; Sm 83:9
Oníd. 4:7Di 20:1
Oníd. 4:9Ond 4:21, 22; 5:24, 26
Oníd. 4:9Joṣ 20:7, 9; 21:32
Oníd. 4:10Ond 5:18
Oníd. 4:11Nọ 24:21; Ond 1:16; 1Sa 15:6
Oníd. 4:11Nọ 10:29
Oníd. 4:12Ond 4:6
Oníd. 4:13Ond 5:20, 21
Oníd. 4:15Ẹk 14:24; Joṣ 10:10
Oníd. 4:16Le 26:7
Oníd. 4:17Ond 5:24
Oníd. 4:17Ond 4:11
Oníd. 4:17Ond 4:1, 2
Oníd. 4:19Ond 5:25
Oníd. 4:21Ond 4:9; 5:26, 27
Oníd. 4:23Heb 11:32, 33
Oníd. 4:24Jẹ 9:25
Oníd. 4:24Di 7:24
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àwọn Onídàájọ́ 4:1-24

Àwọn Onídàájọ́

4 Àmọ́ lẹ́yìn tí Éhúdù kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà.+ 2 Torí náà, Jèhófà fi wọ́n lé ọwọ́ Jábínì ọba Kénáánì,+ tó jọba ní Hásórì. Sísérà ni olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ó sì ń gbé ní Háróṣétì+ ti àwọn orílẹ̀-èdè.* 3 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà,+ torí pé Jábínì* ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin,*+ ogún (20) ọdún ló sì fi fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gidigidi.+

4 Nígbà yẹn, Dèbórà, wòlíì obìnrin+ tó jẹ́ ìyàwó Lápídótù ń ṣe ìdájọ́ ní Ísírẹ́lì. 5 Abẹ́ igi ọ̀pẹ Dèbórà ló máa ń jókòó sí, láàárín Rámà+ àti Bẹ́tẹ́lì,+ ní agbègbè olókè Éfúrémù; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kó ẹjọ́ wọn lọ bá a. 6 Ó ránṣẹ́ sí Bárákì+ ọmọ Ábínóámù láti Kedeṣi-náfútálì,+ ó sì sọ fún un pé: “Ṣebí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti pàṣẹ? ‘Lọ sí* Òkè Tábórì, kí o sì kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin dání látinú àwọn ọmọ Náfútálì àti Sébúlúnì. 7 Màá mú Sísérà, olórí àwọn ọmọ ogun Jábínì wá bá ọ, tòun ti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wá sí odò* Kíṣónì,+ màá sì fi lé ọ lọ́wọ́.’”+

8 Ni Bárákì bá sọ fún un pé: “Tí o bá máa tẹ̀ lé mi, màá lọ, àmọ́ tó ò bá tẹ̀ lé mi, mi ò ní lọ.” 9 Dèbórà fèsì pé: “Ó dájú pé màá bá ọ lọ. Àmọ́ o ò ní gba ògo nínú ogun tí o fẹ́ lọ jà yìí, torí obìnrin ni Jèhófà máa fi Sísérà+ lé lọ́wọ́.” Dèbórà wá gbéra, ó sì tẹ̀ lé Bárákì lọ sí Kédéṣì.+ 10 Bárákì pe Sébúlúnì àti Náfútálì+ sí Kédéṣì, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin sì tẹ̀ lé e. Dèbórà náà bá a lọ.

11 Ó ṣẹlẹ̀ pé Hébà ará Kénì ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn Kénì,+ àwọn àtọmọdọ́mọ Hóbábù, bàbá ìyàwó+ Mósè, ó sì pàgọ́ rẹ̀ sí tòsí igi ńlá ní Sáánánímù, tó wà ní Kédéṣì.

12 Sísérà wá gbọ́ pé Bárákì ọmọ Ábínóámù ti lọ sórí Òkè Tábórì.+ 13 Ojú ẹsẹ̀ ni Sísérà ṣètò gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin* àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀-èdè kí wọ́n lè lọ sí odò* Kíṣónì.+ 14 Dèbórà wá sọ fún Bárákì pé: “Gbéra, torí òní yìí ni Jèhófà máa fi Sísérà lé ọ lọ́wọ́. Ṣebí Jèhófà ń ṣáájú rẹ lọ?” Bárákì sì sọ̀ kalẹ̀ láti orí Òkè Tábórì pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin tó ń tẹ̀ lé e. 15 Jèhófà wá mú kí nǹkan dà rú mọ́ Sísérà lójú+ pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ níwájú idà Bárákì. Nígbà tó yá, Sísérà sọ̀ kalẹ̀ nínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì sá lọ. 16 Bárákì lé àwọn kẹ̀kẹ́ ogun náà àti àwọn ọmọ ogun títí dé Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀-èdè. Bí wọ́n ṣe fi idà pa gbogbo àwọn ọmọ ogun Sísérà nìyẹn; ìkankan nínú wọn ò ṣẹ́ kù.+

17 Àmọ́ Sísérà sá lọ sí àgọ́ Jáẹ́lì+ ìyàwó Hébà+ ará Kénì, torí àlàáfíà wà láàárín Jábínì+ ọba Hásórì àti ìdílé Hébà ará Kénì. 18 Jáẹ́lì sì jáde wá pàdé Sísérà, ó sọ fún un pé: “Wọlé, olúwa mi, máa bọ̀ níbí. Má bẹ̀rù.” Ló bá wọlé sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ tó nípọn bò ó. 19 Ó wá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, fún mi ní omi díẹ̀ mu, torí òùngbẹ ń gbẹ mí.” Ni Jáẹ́lì bá ṣí ìgò awọ kan tí wọ́n rọ wàrà sí, ó sì fún un mu,+ ó wá tún fi aṣọ bò ó. 20 Sísérà sọ fún Jáẹ́lì pé: “Dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́, tí ẹnikẹ́ni bá sì wá bi ọ́ pé, ‘Ṣé ọkùnrin kankan wà níbí?’ kí o sọ pé, ‘Rárá!’”

21 Àmọ́ Jáẹ́lì ìyàwó Hébà mú èèkàn àgọ́, ó sì mú òòlù dání. Nígbà tí ọkùnrin náà ti sùn lọ fọnfọn, tó sì ti rẹ̀ ẹ́, Jáẹ́lì yọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó gbá èèkàn àgọ́ náà wọnú ẹ̀bátí rẹ̀, ó gbá a wọlẹ̀, ọkùnrin náà sì kú.+

22 Bárákì wá Sísérà débẹ̀, Jáẹ́lì sì jáde wá pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé: “Máa bọ̀, jẹ́ kí n fi ọkùnrin tí ò ń wá hàn ọ́.” Bárákì bá tẹ̀ lé e wọlé, ó sì rí òkú Sísérà nílẹ̀, pẹ̀lú èèkàn àgọ́ tí Jáẹ́lì gbá wọnú ẹ̀bátí rẹ̀.

23 Ọjọ́ yẹn ni Ọlọ́run mú kí apá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ká+ Jábínì ọba Kénáánì. 24 Ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì túbọ̀ ń ran Jábínì ọba Kénáánì,+ títí wọ́n fi pa Jábínì ọba Kénáánì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́