ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 19
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Jéhù bá Jèhóṣáfátì wí (1-3)

      • Àwọn àtúnṣe tí Jèhóṣáfátì ṣe (4-11)

2 Kíróníkà 19:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

  • *

    Tàbí “ní àlàáfíà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 18:31, 32

2 Kíróníkà 19:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:1
  • +2Kr 16:7
  • +1Ọb 21:25
  • +Sm 139:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2021, ojú ìwé 3

2 Kíróníkà 19:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

  • *

    Tàbí “ọkàn rẹ ti múra tán.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 14:1, 13
  • +2Kr 17:3-6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2015, ojú ìwé 11-12

    12/1/2005, ojú ìwé 21

    7/1/2003, ojú ìwé 17

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 245

2 Kíróníkà 19:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 17:14, 15
  • +2Kr 15:8

2 Kíróníkà 19:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 16:18

2 Kíróníkà 19:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 1:16, 17; Sm 82:1

2 Kíróníkà 19:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 18:21
  • +Jẹ 18:25; Di 32:4
  • +Iṣe 10:34; Ro 2:11; 1Pe 1:17
  • +Di 10:17; 16:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2011, ojú ìwé 28

2 Kíróníkà 19:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:9; 21:5; 25:1

2 Kíróníkà 19:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn tó pa pọ̀.”

2 Kíróníkà 19:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:8

2 Kíróníkà 19:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pẹ̀lú ohun rere.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mal 2:7
  • +2Kr 15:2

Àwọn míì

2 Kíró. 19:12Kr 18:31, 32
2 Kíró. 19:21Ọb 16:1
2 Kíró. 19:22Kr 16:7
2 Kíró. 19:21Ọb 21:25
2 Kíró. 19:2Sm 139:21
2 Kíró. 19:31Ọb 14:1, 13
2 Kíró. 19:32Kr 17:3-6
2 Kíró. 19:4Joṣ 17:14, 15
2 Kíró. 19:42Kr 15:8
2 Kíró. 19:5Di 16:18
2 Kíró. 19:6Di 1:16, 17; Sm 82:1
2 Kíró. 19:7Ẹk 18:21
2 Kíró. 19:7Jẹ 18:25; Di 32:4
2 Kíró. 19:7Iṣe 10:34; Ro 2:11; 1Pe 1:17
2 Kíró. 19:7Di 10:17; 16:19
2 Kíró. 19:8Di 17:9; 21:5; 25:1
2 Kíró. 19:10Di 17:8
2 Kíró. 19:11Mal 2:7
2 Kíró. 19:112Kr 15:2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 19:1-11

Kíróníkà Kejì

19 Lẹ́yìn náà, Jèhóṣáfátì ọba Júdà pa dà sí ilé* rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù láìséwu.*+ 2 Jéhù+ ọmọ Hánáánì+ aríran jáde lọ bá Ọba Jèhóṣáfátì, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé èèyàn burúkú ló yẹ kí o máa ràn lọ́wọ́,+ ṣé àwọn tó kórìíra Jèhófà ló sì yẹ kí o nífẹ̀ẹ́?+ Nítorí èyí, ìbínú Jèhófà ru sí ọ. 3 Síbẹ̀, àwọn ohun rere kan wà tí a rí nínú rẹ,+ nítorí o ti mú àwọn òpó òrìṣà* kúrò ní ilẹ̀ yìí, o sì ti múra ọkàn rẹ sílẹ̀* láti wá Ọlọ́run tòótọ́.”+

4 Jèhóṣáfátì ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, ó sì tún jáde lọ sáàárín àwọn èèyàn náà láti Bíá-ṣébà dé agbègbè olókè Éfúrémù,+ kó lè mú wọn pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+ 5 Ó tún yan àwọn onídàájọ́ káàkiri ilẹ̀ náà ní gbogbo àwọn ìlú olódi Júdà, láti ìlú dé ìlú.+ 6 Ó sọ fún àwọn onídàájọ́ náà pé: “Ẹ fiyè sí ohun tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí kì í ṣe èèyàn lẹ̀ ń ṣojú fún tí ẹ bá ń dájọ́, Jèhófà ni, ó sì wà pẹ̀lú yín nígbà tí ẹ bá ń ṣe ìdájọ́.+ 7 Ẹ jẹ́ kí ìbẹ̀rù Jèhófà wà lọ́kàn yín.+ Ẹ máa kíyè sára nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí pé kò sí àìṣẹ̀tọ́,+ kò sí ojúsàájú,+ bẹ́ẹ̀ ni kò sí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.”+

8 Ní Jerúsálẹ́mù, Jèhóṣáfátì tún yan àwọn kan lára àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn olórí agbo ilé Ísírẹ́lì láti máa ṣe onídàájọ́ fún Jèhófà àti láti máa yanjú àwọn ẹjọ́ fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.+ 9 Ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ máa ṣe láti fi hàn pé ẹ bẹ̀rù Jèhófà nìyí, kí ẹ sì ṣe é pẹ̀lú ìṣòtítọ́ àti gbogbo ọkàn yín:* 10 Nígbà tí àwọn arákùnrin yín bá wá láti ìlú wọn, tí wọ́n gbé ẹjọ́ tó jẹ mọ́ ìtàjẹ̀sílẹ̀+ tàbí ìbéèrè nípa òfin, àṣẹ, àwọn ìlànà tàbí àwọn ìdájọ́ wá, kí ẹ kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má bàa jẹ̀bi lọ́dọ̀ Jèhófà; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìbínú rẹ̀ máa wá sórí ẹ̀yin àti àwọn arákùnrin yín. Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí kí ẹ má bàa jẹ̀bi. 11 Amaráyà olórí àlùfáà rèé, òun ni olórí yín nínú gbogbo ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ti Jèhófà.+ Sebadáyà ọmọ Íṣímáẹ́lì ni olórí ilé Júdà nínú gbogbo ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ti ọba. Àwọn ọmọ Léfì yóò sì jẹ́ aláṣẹ yín. Ẹ jẹ́ alágbára, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀, kí Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn tó ń ṣe rere.”*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́