ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

      • Ìwẹ̀mọ́ lẹ́yìn tí obìnrin bá bímọ (1-8)

Léfítíkù 12:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Tí ọlẹ̀ bá sọ nínú obìnrin kan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2012, ojú ìwé 17-18

    5/15/2004, ojú ìwé 23

Léfítíkù 12:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọ ọmọ náà nílà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:12; 21:4; Lk 1:59; 2:21, 22; Jo 7:22

Léfítíkù 12:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2004, ojú ìwé 23

Léfítíkù 12:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 1:10

Léfítíkù 12:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 1:14; 5:7; 14:21, 22; Lk 2:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2004, ojú ìwé 23

Àwọn míì

Léf. 12:2Le 15:19
Léf. 12:3Jẹ 17:12; 21:4; Lk 1:59; 2:21, 22; Jo 7:22
Léf. 12:6Le 1:10
Léf. 12:8Le 1:14; 5:7; 14:21, 22; Lk 2:24
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Léfítíkù 12:1-8

Léfítíkù

12 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí obìnrin kan bá lóyún,* tó sì bímọ ọkùnrin, ọjọ́ méje ni kí obìnrin náà fi jẹ́ aláìmọ́, bó ṣe jẹ́ ní àwọn ọjọ́ ìdọ̀tí nígbà tó ń ṣe nǹkan oṣù.+ 3 Ní ọjọ́ kẹjọ, kí wọ́n dá adọ̀dọ́+ ọmọkùnrin náà.* 4 Kí obìnrin náà máa wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) tó tẹ̀ lé e. Kò gbọ́dọ̀ fara kan ohun mímọ́ kankan, kò sì gbọ́dọ̀ wá sínú ibi mímọ́ títí ọjọ́ ìwẹ̀mọ́ rẹ̀ yóò fi pé.

5 “‘Tí ọmọ tó bí bá jẹ́ obìnrin, ọjọ́ mẹ́rìnlá (14) ni kó fi jẹ́ aláìmọ́, bó ṣe máa ń jẹ́ aláìmọ́ tó bá ń ṣe nǹkan oṣù. Kó máa wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) tó tẹ̀ lé e. 6 Tí ọjọ́ ìwẹ̀mọ́ rẹ̀ fún ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin bá pé, kó mú ọmọ àgbò ọlọ́dún kan wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún àlùfáà láti fi rú ẹbọ sísun,+ kó sì mú ọmọ ẹyẹlé tàbí oriri kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 7 Kí àlùfáà mú un wá síwájú Jèhófà, kó ṣe ètùtù fún obìnrin náà, á sì mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ tó ń dà lára rẹ̀. Èyí ni òfin nípa obìnrin tó bímọ ọkùnrin tàbí obìnrin. 8 Tí agbára rẹ̀ ò bá gbé àgùntàn, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì,+ ọ̀kan fún ẹbọ sísun, ìkejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí àlùfáà ṣe ètùtù fún un, obìnrin náà á sì mọ́.’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́