ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 38
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Júdà àti Támárì (1-30)

Jẹ́nẹ́sísì 38:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 24:2, 3; 28:1

Jẹ́nẹ́sísì 38:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 26:19

Jẹ́nẹ́sísì 38:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Júdà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:29, 31

Jẹ́nẹ́sísì 38:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 1:3

Jẹ́nẹ́sísì 38:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 25:5, 6; Mt 22:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1715

Jẹ́nẹ́sísì 38:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Rut 4:6
  • +Di 25:7, 9

Jẹ́nẹ́sísì 38:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 2:3

Jẹ́nẹ́sísì 38:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 26:19

Jẹ́nẹ́sísì 38:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 38:2
  • +Jẹ 38:1
  • +Joṣ 15:10, 12; Ond 14:1

Jẹ́nẹ́sísì 38:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 25:5

Jẹ́nẹ́sísì 38:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2004, ojú ìwé 30

Jẹ́nẹ́sísì 38:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 38:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2004, ojú ìwé 30

Jẹ́nẹ́sísì 38:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:42; 1Ọb 21:8

Jẹ́nẹ́sísì 38:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 38:1

Jẹ́nẹ́sísì 38:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 21:9

Jẹ́nẹ́sísì 38:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 38:16, 18

Jẹ́nẹ́sísì 38:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 38:11; Di 25:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2004, ojú ìwé 29

Jẹ́nẹ́sísì 38:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ya,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abẹ́ tó ya.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:12; Rut 4:12; 1Kr 2:4; Lk 3:23, 33

Jẹ́nẹ́sísì 38:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 1:3

Àwọn míì

Jẹ́n. 38:2Jẹ 24:2, 3; 28:1
Jẹ́n. 38:3Nọ 26:19
Jẹ́n. 38:5Joṣ 19:29, 31
Jẹ́n. 38:6Mt 1:3
Jẹ́n. 38:8Di 25:5, 6; Mt 22:24
Jẹ́n. 38:9Rut 4:6
Jẹ́n. 38:9Di 25:7, 9
Jẹ́n. 38:101Kr 2:3
Jẹ́n. 38:11Nọ 26:19
Jẹ́n. 38:12Jẹ 38:2
Jẹ́n. 38:12Jẹ 38:1
Jẹ́n. 38:12Joṣ 15:10, 12; Ond 14:1
Jẹ́n. 38:14Di 25:5
Jẹ́n. 38:16Jẹ 38:11
Jẹ́n. 38:18Jẹ 41:42; 1Ọb 21:8
Jẹ́n. 38:20Jẹ 38:1
Jẹ́n. 38:24Le 21:9
Jẹ́n. 38:25Jẹ 38:16, 18
Jẹ́n. 38:26Jẹ 38:11; Di 25:5
Jẹ́n. 38:29Jẹ 46:12; Rut 4:12; 1Kr 2:4; Lk 3:23, 33
Jẹ́n. 38:30Mt 1:3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 38:1-30

Jẹ́nẹ́sísì

38 Ní àkókò yẹn, Júdà kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì pàgọ́ rẹ̀ sí tòsí ọkùnrin ará Ádúlámù kan tó ń jẹ́ Hírà. 2 Ibẹ̀ ni Júdà ti rí ọmọbìnrin ara Kénáánì+ kan tó ń jẹ́ Ṣúà. Ó mú un, ó bá a lò pọ̀, 3 ó sì lóyún. Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Éérì.+ 4 Ó tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ónánì. 5 Ó tún bí ọmọkùnrin míì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣélà. Ìlú Ákísíbù+ ni ó* wà nígbà tí obìnrin náà bí i.

6 Nígbà tó yá, Júdà fẹ́ ìyàwó fún Éérì àkọ́bí rẹ̀, Támárì+ ni orúkọ rẹ̀. 7 Àmọ́ inú Jèhófà ò dùn sí Éérì, àkọ́bí Júdà; torí náà, Jèhófà pa á. 8 Torí ìyẹn, Júdà sọ fún Ónánì pé: “Bá ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ lò pọ̀, kí o ṣú u lópó, kí o sì mú kí ẹ̀gbọ́n+ rẹ ní ọmọ.” 9 Àmọ́ Ónánì mọ̀ pé ọmọ náà ò ní jẹ́ tòun.+ Torí náà, nígbà tó bá ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lò pọ̀, ó fi àtọ̀ rẹ̀ ṣòfò sórí ilẹ̀, kí ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀ má bàa ní ọmọ. 10 Ohun tó ṣe yìí burú lójú Jèhófà; torí náà, ó pa+ òun náà. 11 Júdà sọ fún Támárì ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé: “Lọ máa ṣe opó ní ilé bàbá rẹ títí Ṣélà ọmọ mi yóò fi dàgbà,” torí ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Òun náà lè kú bíi ti àwọn ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀.” Támárì wá lọ ń gbé ní ilé bàbá rẹ̀.

12 Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ìyàwó Júdà tó jẹ́ ọmọ Ṣúà+ kú. Júdà ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, lẹ́yìn náà, òun àti Hírà ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Ádúlámù+ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀ ní Tímúnà.+ 13 Àwọn kan sọ fún Támárì pé: “Bàbá ọkọ rẹ ń lọ sí Tímúnà láti rẹ́ irun àwọn àgùntàn rẹ̀.” 14 Ló bá bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó fi aṣọ bojú, ó sì fi ìborùn borí rẹ̀. Ó wá jókòó sí ẹnu ọ̀nà Énáímù, tó wà ní ọ̀nà Tímúnà, torí ó rí i pé Ṣélà ti dàgbà, bàbá rẹ̀ kò sì tíì sọ pé kí òun di ìyàwó+ Ṣélà.

15 Nígbà tí Júdà rí i, ó rò pé aṣẹ́wó ni, torí ó fi nǹkan bojú. 16 Torí náà, ó yà sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n bá ọ lò pọ̀,” ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé ìyàwó ọmọ+ òun ni. Obìnrin náà bi í pé: “Kí lo máa fún mi tí o bá bá mi lò pọ̀?” 17 Ó fèsì pé: “Màá fi ọmọ ewúrẹ́ kan ránṣẹ́ látinú agbo ẹran mi.” Àmọ́ obìnrin náà sọ pé: “Ṣé o máa fi nǹkan ṣe ìdúró títí dìgbà tí wàá fi ewúrẹ́ náà ránṣẹ́?” 18 Ó bi í pé: “Kí ni kí n fi ṣe ìdúró fún ọ?” Obìnrin náà fèsì pé: “Òrùka èdìdì+ rẹ, okùn rẹ àti ọ̀pá ọwọ́ rẹ.” Ló bá kó o fún un, ó sì bá a lò pọ̀, obìnrin náà sì lóyún fún un. 19 Lẹ́yìn náà, ó gbéra, ó sì kúrò níbẹ̀, ó mú ìborùn kúrò, ó sì wọ aṣọ opó rẹ̀.

20 Júdà fi ọmọ ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀ ará Ádúlámù,+ kó bàa lè gba ohun tó fi ṣe ìdúró pa dà lọ́wọ́ obìnrin náà, àmọ́ kò rí i. 21 Ó bi àwọn tó ń gbé ibi tí obìnrin náà wà pé: “Ibo ni aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì tó wà ní Énáímù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà yẹn wà?” Àmọ́ wọ́n fèsì pé: “Aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì kankan ò sí níbí yìí rí.” 22 Níkẹyìn, ó pa dà sọ́dọ̀ Júdà, ó sì sọ pé: “Mi ò rí i, àwọn èèyàn ibẹ̀ náà sọ pé, ‘Aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì kankan ò sí níbí yìí rí.’” 23 Júdà wá sọ pé: “Jẹ́ kó máa mú un lọ, ká má bàa di ẹni àbùkù. Mo kúkú ti fi ọmọ ewúrẹ́ yìí ránṣẹ́, ṣùgbọ́n o ò rí obìnrin náà.”

24 Àmọ́, ní nǹkan bí oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n sọ fún Júdà pé: “Támárì ìyàwó ọmọ rẹ ṣe aṣẹ́wó, ó sì ti lóyún nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ṣe.” Ni Júdà bá sọ pé: “Ẹ mú un jáde ká sì sun ún.”+ 25 Nígbà tí wọ́n mú un jáde, ó ránṣẹ́ sí bàbá ọkọ rẹ̀ pé: “Ọkùnrin tó ni àwọn nǹkan yìí ló fún mi lóyún.” Ó tún sọ pé: “Jọ̀ọ́, wo òrùka èdìdì yìí, okùn àti ọ̀pá+ yìí kí o lè mọ ẹni tó ni ín.” 26 Ni Júdà bá yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì sọ pé: “Òdodo rẹ̀ ju tèmi lọ, torí mi ò fún un ní Ṣélà ọmọ mi.”+ Kò sì bá a lò pọ̀ mọ́ lẹ́yìn ìyẹn.

27 Nígbà tó tó àkókò tó máa bímọ, ìbejì ló wà nínú rẹ̀. 28 Bó ṣe ń bímọ, ọ̀kan na ọwọ́ jáde, ni agbẹ̀bí bá mú òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, ó sì so ó mọ́ ọwọ́ rẹ̀, ó ní: “Èyí ló kọ́kọ́ jáde.” 29 Àmọ́ bó ṣe fa ọwọ́ rẹ̀ pa dà, arákùnrin rẹ̀ jáde, obìnrin náà sì sọ pé: “Wo bí o ṣe dọ́gbẹ́ sí ìyá rẹ lára kí o tó lè jáde!” Torí náà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Pérésì.*+ 30 Lẹ́yìn náà, arákùnrin rẹ̀ jáde, òun ni wọ́n so òwú pupa mọ́ lọ́wọ́, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Síírà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́