ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 29
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Sámúẹ́lì

      • Àwọn Filísínì kò fọkàn tán Dáfídì (1-11)

1 Sámúẹ́lì 29:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 28:1
  • +Joṣ 19:17, 18; 1Sa 29:11

1 Sámúẹ́lì 29:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 28:2

1 Sámúẹ́lì 29:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 27:7, 12

1 Sámúẹ́lì 29:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 12:19
  • +1Sa 14:21

1 Sámúẹ́lì 29:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:7; 21:11

1 Sámúẹ́lì 29:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 21:10; 27:2
  • +1Sa 28:2
  • +1Sa 27:11, 12
  • +1Sa 29:3, 9

1 Sámúẹ́lì 29:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 27:12

1 Sámúẹ́lì 29:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:17, 18; 1Sa 29:1

Àwọn míì

1 Sám. 29:11Sa 28:1
1 Sám. 29:1Joṣ 19:17, 18; 1Sa 29:11
1 Sám. 29:21Sa 28:2
1 Sám. 29:31Sa 27:7, 12
1 Sám. 29:41Kr 12:19
1 Sám. 29:41Sa 14:21
1 Sám. 29:51Sa 18:7; 21:11
1 Sám. 29:61Sa 21:10; 27:2
1 Sám. 29:61Sa 28:2
1 Sám. 29:61Sa 27:11, 12
1 Sám. 29:61Sa 29:3, 9
1 Sám. 29:91Sa 27:12
1 Sám. 29:11Joṣ 19:17, 18; 1Sa 29:1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Sámúẹ́lì 29:1-11

Sámúẹ́lì Kìíní

29 Àwọn Filísínì+ kó gbogbo ọmọ ogun wọn jọ sí Áfékì, nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ìsun tí ó wà ní Jésírẹ́lì.+ 2 Àwọn alákòóso Filísínì ń kọjá lọ pẹ̀lú ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ sì ń rìn bọ̀ lẹ́yìn pẹ̀lú Ákíṣì.+ 3 Àmọ́ àwọn ìjòyè Filísínì sọ pé: “Kí ni àwọn Hébérù yìí ń wá níbí?” Ákíṣì dá àwọn ìjòyè Filísínì lóhùn pé: “Dáfídì ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì rèé, ó ti tó ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ+ tí ó ti wà lọ́dọ̀ mi. Mi ò rí ohun tí kò tọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti sá wá sọ́dọ̀ mi títí di òní yìí.” 4 Àmọ́ inú bí àwọn ìjòyè Filísínì sí Ákíṣì gan-an, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ní kí ọkùnrin náà pa dà.+ Kó pa dà sí àyè tí o yàn án sí. Má ṣe jẹ́ kó bá wa lọ sójú ogun, kó má bàa yíjú pa dà sí wa lójú ogun.+ Ọ̀nà wo ni ì bá tún gbà wá ojú rere olúwa rẹ̀ ju pé kó fi orí àwọn èèyàn wa lé e lọ́wọ́? 5 Ṣé kì í ṣe Dáfídì tí wọ́n kọrin fún, tí wọ́n sì ń jó fún nìyí, tí wọ́n ń sọ pé:

‘Sọ́ọ̀lù ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀tá,

Àmọ́ Dáfídì pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọ̀tá’?”+

6 Nítorí náà, Ákíṣì+ pe Dáfídì, ó sì sọ fún un pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, olóòótọ́ ni ọ́, inú mi sì dùn sí i pé kí o bá àwọn ọmọ ogun mi jáde ogun,+ torí mi ò rí ohun tí kò tọ́ lọ́wọ́ rẹ láti ọjọ́ tí o ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.+ Àmọ́ àwọn alákòóso kò fọkàn tán ọ.+ 7 Torí náà, pa dà ní àlàáfíà, má sì ṣe ohunkóhun tí á bí àwọn alákòóso Filísínì nínú.” 8 Àmọ́, Dáfídì sọ fún Ákíṣì pé: “Kí ló dé? Kí ni mo ṣe? Ohun tí kò tọ́ wo lo rí lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ láti ọjọ́ tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ títí di òní yìí? Kí nìdí tí mi ò fi lè tẹ̀ lé ọ, kí n sì bá àwọn ọ̀tá olúwa mi ọba jà?” 9 Ni Ákíṣì bá dá Dáfídì lóhùn pé: “Lójú tèmi, ìwà rẹ dára bíi ti áńgẹ́lì Ọlọ́run.+ Ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Filísínì ti sọ pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ó bá wa lọ sójú ogun.’ 10 Torí náà, dìde ní àárọ̀ kùtù pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ tí ó bá ọ wá; kí ẹ gbéra, kí ẹ sì lọ ní àárọ̀ kùtù gbàrà tí ilẹ̀ bá ti mọ́.”

11 Torí náà, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ dìde ní àárọ̀ láti pa dà sí ilẹ̀ àwọn Filísínì, àwọn Filísínì sì lọ sí Jésírẹ́lì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́