Jóòbù
18 Bílídádì+ ọmọ Ṣúáhì fèsì pé:
2 “Ìgbà wo lẹ ò ní sọ̀rọ̀ báyìí mọ́?
Ẹ lo òye, ká lè wá sọ̀rọ̀.
4 Tí o bá tiẹ̀ fa ara* rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ torí inú tó ń bí ọ,
Ṣé a máa pa ayé tì nítorí rẹ ni,
Àbí àpáta máa ṣí kúrò ní àyè rẹ̀?
5 Àní, a máa pa iná ẹni burúkú,
Ọwọ́ iná rẹ̀ kò sì ní tàn.+
6 Ó dájú pé ìmọ́lẹ̀ inú àgọ́ rẹ̀ máa di òkùnkùn,
A sì máa fẹ́ fìtílà tó wà lórí rẹ̀ pa.
7 Ìrìn tó ń fi tagbáratagbára rìn dín kù,
Ìmọ̀ràn ara rẹ̀ sì máa gbé e ṣubú.+
8 Torí ẹsẹ̀ rẹ̀ máa mú un wọnú àwọ̀n,
Ó sì máa rìn gbéregbère wọnú àwọn okùn rẹ̀.
9 Pańpẹ́ máa mú un ní gìgísẹ̀;
Ìdẹkùn á sì mú un.+
10 Okùn kan ti wà nípamọ́ dè é lórí ilẹ̀,
Pańpẹ́ sì wà lójú ọ̀nà rẹ̀.
11 Jìnnìjìnnì bò ó yí ká,+
Ó sì ń sá tẹ̀ lé e ní ẹsẹ̀ rẹ̀.
13 Awọ ara rẹ̀ jẹ dà nù;
Àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí tó lágbára jù* jẹ apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ run.
16 Gbòǹgbò rẹ̀ máa gbẹ lábẹ́ rẹ̀,
Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì máa rọ lórí rẹ̀.
17 Wọn ò ní rántí rẹ̀ mọ́ ní ayé,
Wọn ò sì ní mọ orúkọ rẹ̀* ní àdúgbò.
18 Wọ́n máa lé e kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ sínú òkùnkùn,
Wọ́n sì máa lé e kúrò ní ilẹ̀ tó ń méso jáde.
19 Kò ní ní ọmọ àti àtọmọdọ́mọ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀,
Kò sì ní sí ẹni tó máa yè bọ́ níbi tó ń gbé.*
20 Tí ọjọ́ rẹ̀ bá dé, àwọn èèyàn tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn máa bẹ̀rù,
Jìnnìjìnnì sì máa bo àwọn èèyàn tó wà ní Ìlà Oòrùn.
21 Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àgọ́ ẹni burúkú nìyí
Àti ibùgbé ẹni tí kò mọ Ọlọ́run.”