ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Oníwàásù 6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù

      • Ọ̀pọ̀ ohun ìní láìsí ìgbádùn (1-6)

      • Gbádùn ohun tí o ní nísinsìnyí (7-12)

Oníwàásù 6:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Àjálù.”

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Oníwàásù 6:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí ọkàn rẹ̀.”

  • *

    Tàbí “kí ibojì tó jẹ́ tirẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 4:2, 3

Oníwàásù 6:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ní ìsinmi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 3:11, 13; 14:1

Oníwàásù 6:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 30:23; Onw 3:20; Ro 5:12

Oníwàásù 6:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn rẹ̀ kì í.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 3:19; Owe 16:26

Oníwàásù 6:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “máa rìn níwájú àwọn alààyè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 49:10; Onw 2:15, 16

Oníwàásù 6:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kí ọkàn rẹ̀ máa rìn káàkiri.”

  • *

    Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    8/2021, ojú ìwé 21

    Jí!: Bá A Ṣe Lè Fọgbọ́n Lo Àkókò Wa

    4/2011, ojú ìwé 31

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 15

Oníwàásù 6:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbèjà ara rẹ̀ níwájú ẹni tó lágbára jù ú lọ.”

Oníwàásù 6:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “nǹkan.”

Oníwàásù 6:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 29:15; Job 8:9; 14:1, 2; Sm 102:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/1997, ojú ìwé 11

Àwọn míì

Oníw. 6:3Onw 4:2, 3
Oníw. 6:5Job 3:11, 13; 14:1
Oníw. 6:6Job 30:23; Onw 3:20; Ro 5:12
Oníw. 6:7Jẹ 3:19; Owe 16:26
Oníw. 6:8Sm 49:10; Onw 2:15, 16
Oníw. 6:121Kr 29:15; Job 8:9; 14:1, 2; Sm 102:11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Oníwàásù 6:1-12

Oníwàásù

6 Àdánù* míì wà tí mo ti rí lábẹ́ ọ̀run,* ó sì máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn: 2 Ọlọ́run tòótọ́ fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀ àti ohun ìní àti ògo, tí kò fi ṣaláìní ohunkóhun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́; síbẹ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kò jẹ́ kó gbádùn àwọn ohun náà, àmọ́ ó jẹ́ kí àlejò gbádùn wọn. Asán ni èyí àti ìpọ́njú tó lágbára. 3 Tí ọkùnrin kan bá bímọ ní ọgọ́rùn-ún ìgbà, tó lo ọ̀pọ̀ ọdún láyé, tó sì darúgbó, síbẹ̀ tí* kò gbádùn àwọn ohun rere tó ní kó tó wọnú sàréè,* ohun tí màá sọ ni pé ọmọ tí wọ́n bí ní òkú sàn jù ú lọ.+ 4 Torí pé ẹni yìí wá lásán, ó sì lọ nínú òkùnkùn, òkùnkùn bo orúkọ rẹ̀ mọ́lẹ̀. 5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rí oòrùn, kò sì mọ nǹkan kan, ó ṣì sàn* ju ẹni ìṣáájú lọ.+ 6 Kí làǹfààní kéèyàn gbé ẹgbẹ̀rún ọdún láyé ní ìlọ́po méjì, àmọ́ kó má gbádùn nǹkan kan? Torí pé ibì kan náà ni gbogbo èèyàn ń lọ.+

7 Gbogbo iṣẹ́ àṣekára téèyàn ń ṣe, torí kó lè rí nǹkan fi sẹ́nu ni;+ síbẹ̀ kì í* yó. 8 Nítorí àǹfààní wo ni ọlọ́gbọ́n ní lórí òmùgọ̀?+ Tàbí àǹfààní kí ló jẹ́ fún aláìní pé ó mọ bí èèyàn ṣe ń tọ́jú ara rẹ̀?* 9 Ó sàn kéèyàn máa gbádùn ohun tí ojú rẹ̀ rí ju kó máa dààmú lórí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́.* Asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo.*

10 Ohunkóhun tó bá wà, ó ti ní orúkọ tẹ́lẹ̀, a ti mọ ohun tí èèyàn jẹ́; kò sì lè bá ẹni tó lágbára jù ú lọ jiyàn.* 11 Bí ọ̀rọ̀* bá ṣe pọ̀ náà ni asán á ṣe pọ̀, àǹfààní wo sì ni èèyàn máa rí nínú wọn? 12 Ta ló mọ ohun tó dára jù lọ fún èèyàn láti fi ayé rẹ̀ ṣe láàárín ọjọ́ díẹ̀ tó máa fi gbé ìgbé ayé asán, èyí tó máa kọjá lọ bí òjìji?+ Àbí ta ló lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run* fún èèyàn lẹ́yìn tó bá ti lọ?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́