Jóòbù
4 Élífásì+ ará Témánì wá fèsì pé:
2 “Tí ẹnì kan bá fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀, ṣebí wàá ní sùúrù?
Àbí ta ló lè dákẹ́ kó má sọ̀rọ̀?
3 Òótọ́ ni pé o ti tọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn sọ́nà,
O sì máa ń fún àwọn ọwọ́ tí kò lágbára lókun.
4 Ọ̀rọ̀ rẹ máa ń gbé ẹnikẹ́ni tó bá kọsẹ̀ dìde,
O sì máa ń fún àwọn tí orúnkún wọn yẹ̀ lókun.
5 Àmọ́ ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ báyìí, ó sì wá mu ọ́ lómi;*
Ó kàn ọ́, ìdààmú sì bá ọ.
6 Ṣé ìbẹ̀rù tí o ní fún Ọlọ́run kò fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ ni?
Ṣé ìwà títọ́+ rẹ ò fún ọ ní ìrètí ni?
7 Jọ̀ọ́ rántí: Aláìṣẹ̀ wo ló ṣègbé rí?
Ìgbà wo ni àwọn adúróṣinṣin pa run rí?
8 Ohun tí mo rí ni pé àwọn tó ń túlẹ̀ láti gbin* ohun tó burú
Àti àwọn tó ń gbin wàhálà máa kórè ohun tí wọ́n bá gbìn.
9 Èémí Ọlọ́run mú kí wọ́n ṣègbé,
Ìbínú rẹ̀ tó le sì mú kí wọ́n wá sí òpin.
10 Kìnnìún ń ké ramúramù, ọmọ kìnnìún sì ń kùn,
Àmọ́ eyín àwọn kìnnìún tó lágbára* pàápàá kán.
11 Kìnnìún ṣègbé torí kò rí ẹran pa jẹ,
Àwọn ọmọ kìnnìún sì tú ká.
12 A sọ ọ̀rọ̀ kan fún mi ní àṣírí,
A sì sọ ọ́ sí mi létí wúyẹ́wúyẹ́.
13 Nínú ìran tí mo rí ní òru, tó ń da ọkàn láàmú,
Nígbà tí àwọn èèyàn ti sùn lọ fọnfọn,
14 Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n rìrì lákọlákọ,
Ìbẹ̀rù bò mí wọnú egungun.
15 Ẹ̀mí kan kọjá lójú mi;
Irun ara mi dìde.
16 Ó wá dúró sójú kan,
Àmọ́ mi ò dá a mọ̀.
Ohun kan wà níwájú mi;
Gbogbo nǹkan pa rọ́rọ́, mo wá gbọ́ ohùn kan tó sọ pé:
17 ‘Ṣé ẹni kíkú lè jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run lọ?
Ṣé ẹnì kan lè mọ́ ju Ẹni tó dá a lọ?’
18 Wò ó! Kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,
Ó sì ń wá àṣìṣe àwọn áńgẹ́lì* rẹ̀.
19 Mélòómélòó wá ni àwọn tó ń gbé ilé alámọ̀,
Tí ìpìlẹ̀ wọn wà nínú iyẹ̀pẹ̀,+
Tí wọ́n rọrùn láti tẹ̀ rẹ́ bí òólá!*
20 A tẹ̀ wọ́n rẹ́ pátápátá láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀;
Wọ́n ṣègbé títí láé, ẹnì kankan ò sì kíyè sí i.
21 Ṣebí wọ́n dà bí àgọ́ tí wọ́n fa okùn rẹ̀ yọ?
Wọ́n kú láìní ọgbọ́n.