Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù Ẹ́KÍSÓDÙ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i ní Íjíbítì (1-7) Fáráò ń fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (8-14) Àwọn agbẹ̀bí tó bẹ̀rù Ọlọ́run dá ẹ̀mí sí (15-22) 2 Wọ́n bí Mósè (1-4) Ọmọbìnrin Fáráò fi Mósè ṣe ọmọ rẹ̀ (5-10) Mósè sá lọ sí Mídíánì, ó sì fẹ́ Sípórà (11-22) Ọlọ́run gbọ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń kérora (23-25) 3 Mósè àti igi ẹlẹ́gùn-ún tó ń jó (1-12) Jèhófà sọ ìtúmọ̀ orúkọ Rẹ̀ (13-15) Jèhófà fún Mósè ní ìtọ́ni (16-22) 4 Iṣẹ́ àmì mẹ́ta tí Mósè máa ṣe (1-9) Mósè ní òun ò kúnjú ìwọ̀n (10-17) Mósè pa dà sí Íjíbítì (18-26) Mósè àti Áárónì tún jọ pàdé (27-31) 5 Mósè àti Áárónì lọ bá Fáráò (1-5) Wọ́n túbọ̀ fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (6-18) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá Mósè àti Áárónì lẹ́bi (19-23) 6 Ọlọ́run tún ṣèlérí òmìnira ((1-13) Wọn ò mọ orúkọ Jèhófà délẹ̀délẹ̀ (2, 3) Ìlà ìdílé Mósè àti Áárónì (14-27) Mósè tún máa lọ sọ́dọ̀ Fáráò (28-30) 7 Jèhófà fún Mósè lókun (1-7) Ọ̀pá Áárónì di ejò ńlá (8-13) Ìyọnu 1: omi di ẹ̀jẹ̀ (14-25) 8 Ìyọnu 2: àkèré (1-15) Ìyọnu 3: kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ (16-19) Ìyọnu 4: eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ (20-32) Ìyọnu ò dé ilẹ̀ Góṣénì 22, 23) 9 Ìyọnu 5: àwọn ẹran ọ̀sìn kú (1-7) Ìyọnu 6: eéwo yọ sára èèyàn àti ẹranko (8-12) Ìyọnu 7: òjò yìnyín (13-35) Fáráò yóò rí agbára Ọlọ́run (16) Wọ́n á mọ orúkọ Jèhófà (16) 10 Ìyọnu 8: eéṣú (1-20) Ìyọnu 9: òkùnkùn (21-29) 11 Ó kéde ìyọnu kẹwàá (1-10) Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì béèrè ẹ̀bùn (2) 12 Ó fi Ìrékọjá lọ́lẹ̀ (1-28) Wọ́n máa wọ́n ẹ̀jẹ̀ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn (7) Ìyọnu 10: Ó pa àkọ́bí (29-32) Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò ní ilẹ̀ náà (33-42) 430 ọdún parí (40, 41) Ìtọ́ni fún àwọn tó fẹ́ ṣe Ìrékọjá (43-51) 13 Ti Jèhófà ni gbogbo àkọ́bí tó jẹ́ akọ (1, 2) Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú (3-10) Kí wọ́n ya gbogbo àkọ́bí tó jẹ́ akọ sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run (11-16) Ọlọ́run darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ọ̀nà Òkun Pupa (17-20) Ọwọ̀n ìkùukùu àti ọwọ̀n iná (21, 22) 14 Ísírẹ́lì dé òkun (1-4) Fáráò ń lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (5-14) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá Òkun Pupa (15-25) Àwọn ará Íjíbítì rì sínú òkun (26-28) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà (29-31) 15 Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọrin ìṣẹ́gun (1-19) Míríámù fi orin dáhùn pa dà (20, 21) Omi tó korò wá dùn (22-27) 16 Àwọn èèyàn ń ráhùn torí oúnjẹ (1-3) Jèhófà gbọ́ ìráhùn wọn (4-12) Ó fún wọn ní ẹyẹ àparò àti mánà (13-21) Kò sí mánà lọ́jọ́ Sábáàtì (22-30) Wọ́n tọ́jú mánà fún ìrántí (31-36) 17 Wọ́n ráhùn pé wọn ò rí omi mu ní Hórébù (1-4) Omi jáde látinú àpáta (5-7) Àwọn ọmọ Ámálékì gbógun ja Ísírẹ́lì, àmọ́ wọn ò borí (8-16) 18 Jẹ́tírò àti Sípórà dé (1-12) Jẹ́tírò ní kó yan àwọn adájọ́ (13-27) 19 Ní Òkè Sínáì (1-25) Ísírẹ́lì yóò di ìjọba àwọn àlùfáà (5, 6) Ó sọ àwọn èèyàn di mímọ́ láti pàdé Ọlọ́run (14, 15) 20 Òfin Mẹ́wàá (1-17) Ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí dẹ́rù bà wọ́n (18-21) Ìtọ́ni nípa ìjọsìn (22-26) 21 Ìdájọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tẹ̀ lé (1-36) Tí wọ́n bá ra Hébérù ní ẹrú (2-11) Tí ẹnì kan bá hùwà ipá sí ẹnì kejì (12-27) Nípa àwọn ẹranko (28-36) 22 Ìdájọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tẹ̀ lé (1-31) Tí ẹnì kan bá jalè (1-4) Tí ẹnì kan bá ba irè oko ẹlòmíì jẹ́ (5, 6) Nípa àsanfidípò àti ohun ìní (7-15) Nípa fífa ojú wúńdíá mọ́ra (16, 17) Nípa ìjọsìn àti ohun tó tọ́ láwùjọ (18-31) 23 Ìdájọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tẹ̀ lé (1-19) Nípa ìṣòtítọ́ àti ìwà tó tọ́ (1-9) Nípa sábáàtì àti àwọn àjọyọ̀ (10-19) Áńgẹ́lì yóò máa darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (20-26) Gbígba ilẹ̀ àti ààlà (27-33) 24 Àwọn èèyàn gbà láti pa májẹ̀mú mọ́ (1-11) Mósè lọ sórí Òkè Sínáì (12-18) 25 Ọrẹ àgọ́ ìjọsìn (1-9) Àpótí (10-22) Tábìlì (23-30) Ọ̀pá fìtílà (31-40) 26 Àgọ́ ìjọsìn (1-37) Àwọn aṣọ àgọ́ (1-14) Àwọn férémù àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò (15-30) Aṣọ ìdábùú àti aṣọ tí wọ́n máa ta sí ẹnu ọ̀nà (31-37) 27 Pẹpẹ ẹbọ sísun (1-8) Àgbàlá (9-19) Òróró ọ̀pá fìtílà (20, 21) 28 Àwọn aṣọ àlùfáà (1-5) Éfódì (6-14) Aṣọ ìgbàyà (15-30) Úrímù àti Túmímù (30) Aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá (31-35) Láwàní àti àwo dídán (36-39) Àwọn aṣọ míì tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà (40-43) 29 Fífi iṣẹ́ lé àwọn àlùfáà lọ́wọ́ (1-37) Ọrẹ ojoojúmọ́ (38-46) 30 Pẹpẹ tùràrí (1-10) Ìkànìyàn àti owó ètùtù (11-16) Bàsíà bàbà láti máa fi wẹ̀ (17-21) Àkànṣe òróró àfiyanni (22-33) Àwọn èròjà tùràrí mímọ́ (34-38) 31 Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ kún inú àwọn oníṣẹ́ ọnà (1-11) Sábáàtì jẹ́ àmì láàárín Ọlọ́run àti Ísírẹ́lì (12-17) Wàláà òkúta méjì (18) 32 Wọ́n jọ́sìn ère ọmọ màlúù (1-35) Mósè gbọ́ orin tó ṣàjèjì (17, 18) Mósè fọ́ àwọn wàláà òfin túútúú (19) Àwọn ọmọ Léfì ò fi Jèhófà sílẹ̀ (26-29) 33 Ọlọ́run bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí (1-6) Àgọ́ ìpàdé ní ẹ̀yìn ibùdó (7-11) Mósè fẹ́ rí ògo Jèhófà (12-23) 34 Ó gbẹ́ àwọn wàláà òkúta míì (1-4) Mósè rí ògo Jèhófà (5-9) Ọlọ́run tún àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà sọ (10-28) Ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú Mósè (29-35) 35 Àwọn ìtọ́ni Sábáàtì (1-3) Ọrẹ àgọ́ ìjọsìn (4-29) Ọlọ́run fi ẹ̀mí kún inú Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù (30-35) 36 Ọrẹ náà tó, ó ṣẹ́ kù (1-7) Wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn (8-38) 37 Ó ṣe Àpótí (1-9) Tábìlì (10-16) Ọ̀pá fìtílà (17-24) Pẹpẹ tùràrí (25-29) 38 Pẹpẹ ẹbọ sísun (1-7) Ó fi bàbà ṣe bàsíà (8) Àgbàlá (9-20) Wọ́n ka àwọn ohun èlò àgọ́ ìjọsìn (21-31) 39 Wọ́n ṣe àwọn aṣọ àlùfáà (1) Éfódì (2-7) Aṣọ ìgbàyà (8-21) Aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá (22-26) Àwọn aṣọ míì tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà (27-29) Àwo wúrà (30, 31) Mósè yẹ iṣẹ́ tí wọ́n ṣe sí àgọ́ ìjọsìn wò (32-43) 40 Wọ́n to àgọ́ ìjọsìn (1-33) Ògo Jèhófà kún inú àgọ́ ìjọsìn (34-38)