Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Òwe OWE OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ohun tí òwe wà fún (1-7) Ewu tó wà nínú ẹgbẹ́ búburú (8-19) Ọgbọ́n tòótọ́ ń ké jáde ní gbangba (20-33) 2 Ìwúlò ọgbọ́n (1-22) Máa wá ọgbọ́n bí ìṣúra tó fara sin (4) Làákàyè ń dáàbò boni (11) Ìṣekúṣe máa ń fa àjálù (16-19) 3 Jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà (1-12) Fi àwọn ohun ìní rẹ tó níye lórí bọlá fún Jèhófà (9) Ọgbọ́n ń fúnni láyọ̀ (13-18) Ọgbọ́n ń dáàbò boni (19-26) Ìwà tó yẹ ká máa hù sáwọn èèyàn (27-35) Máa ṣe rere fún àwọn èèyàn nígbà tí o bá lè ṣe é (27) 4 Ẹ̀kọ́ ọlọgbọ́n tí bàbá kan kọ́ni (1-27) Ju ohun gbogbo, ní ọgbọ́n (7) Yẹra fún ọ̀nà burúkú (14, 15) Ipa ọ̀nà àwọn olódodo ń mọ́lẹ̀ sí i (18) “Dáàbò bo ọkàn rẹ” (23) 5 Ìkìlọ̀ nítorí obìnrin oníṣekúṣe (1-14) Máa yọ̀ pẹ̀lú aya rẹ (15-23) 6 Ṣọ́ra fún ṣíṣe onídùúró ẹni tó fẹ́ yá owó (1-5) “Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ” (6-11) Ìkà àti aláìwúlò ẹ̀dá (12-15) Ohun méje tí Jèhófà kórìíra (16-19) Ṣọ́ra fún obìnrin burúkú (20-35) 7 Rọ̀ mọ́ àwọn àṣẹ Ọlọ́run, kí o sì wà láàyè (1-5) Ó fa ojú ọ̀dọ́kùnrin aláìmọ̀kan mọ́ra (6-27) “Bí akọ màlúù tí wọ́n ń mú lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ pa á” (22) 8 Ọgbọ́n sọ̀rọ̀ bí èèyàn (1-36) ‘Èmi ni àkọ́bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run’ (22) ‘Gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run’ (30) ‘Mo fẹ́ràn àwọn ọmọ èèyàn’ (31) 9 Ọgbọ́n tòótọ́ ń pe àwọn èèyàn (1-12) “Ọgbọ́n yóò jẹ́ kí ọjọ́ ayé rẹ di púpọ̀” (11) Òmùgọ̀ obìnrin ń pe àwọn èèyàn (13-18) “Omi tí a jí gbé máa ń dùn” (17) ÀWỌN ÒWE SÓLÓMỌ́NÌ (10:1–24:34) 10 Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú bàbá rẹ̀ dùn (1) Ọwọ́ tó ń ṣiṣẹ́ kára ń sọni di ọlọ́rọ̀ (4) Tí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀, àṣìṣe kò ní ṣàì wáyé (19) Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀ (22) Ìbẹ̀rù Jèhófà ń mú kí ẹ̀mí ẹni gùn (27) 11 Ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn tó mọ̀wọ̀n ara wọn (2) Apẹ̀yìndà máa ń fa ìparun bá àwọn ẹlòmíì (9) “Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà” (14) Ẹni tó bá láwọ máa láásìkí (25) Ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀ máa ṣubú (28) 12 Ẹni tó kórìíra ìbáwí kò ní ọgbọ́n (1) “Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni” (18) Wíwá àlàáfíà ń mú kí ayọ̀ wà (20) Ètè tó ń parọ́ jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà (22) Àníyàn ń mú kí ọkàn rẹ̀wẹ̀sì (25) 13 Àwọn tó ń wá ìmọ̀ràn máa ń gbọ́n (10) Ìrètí pípẹ́ máa ń mú ọkàn ṣàìsàn (12) Aṣojú tó jẹ́ olóòótọ́ ń mú ìwòsàn wá (17) Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n (20) Ọ̀nà kan tí a lè gbà fìfẹ́ hàn ni pé ká báni wí (24) 14 Ọkàn èèyàn mọ ìbànújẹ́ rẹ̀ (10) Ọ̀nà tó dà bíi pé ó tọ́ lè yọrí sí ikú (12) Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́ (15) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bá ọlọ́rọ̀ ṣọ̀rẹ́ (20) Ìbàlẹ̀ ọkàn ń mú kí ara lókun (30) 15 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀ (1) Ojú Jèhófà wà níbi gbogbo (3) Àdúrà àwọn adúróṣinṣin máa ń múnú Ọlọ́run dùn (8) Láìsí ìfinúkonú, èrò á dasán (22) Máa ṣe àṣàrò kí o tó dáhùn (28) 16 Jèhófà ń ṣàyẹ̀wò èrò ọkàn (2) Fi gbogbo iṣẹ́ rẹ lé Jèhófà lọ́wọ́ (3) Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni òṣùwọ̀n pípé ti wá (11) Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun (18) Ewú orí jẹ́ adé ẹwà (31) 17 Má fi búburú san rere (13) Kí ìjà tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀ (14) Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo (17) “Ọkàn tó ń yọ̀ jẹ́ oògùn tó dára fún ara” (22) Ẹni tó ní òye máa ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ tó ń sọ (27) 18 Ẹni tó bá ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, ire ara rẹ̀ ló ń wá, kò sì gbọ́n (1) Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tó lágbára (10) Ọrọ̀ kì í ṣe ààbò gidi (11) Ọgbọ́n wà nínú fífi etí sí tọ̀túntòsì (17) Ọ̀rẹ́ kan ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ (24) 19 Ìjìnlẹ̀ òye tí èèyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ (11) Oníjà aya dà bí òrùlé tó ń jò (13) Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni aya olóye ti wá (14) Bá ọmọ wí nígbà tí ìrètí ṣì wà (18) Ọgbọ́n tó wà nínú kéèyàn máa gba ìmọ̀ràn (20) 20 Afiniṣẹ̀sín ni wáìnì (1) Ọ̀lẹ kì í túlẹ̀ nígbà òtútù (4) Èrò ọkàn èèyàn dà bí omi jíjìn (5) Ìkìlọ̀ lórí kéèyàn kánjú jẹ́ ẹ̀jẹ́ (25) Ògo àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn (29) 21 Jèhófà ń darí ọkàn ọba (1) Ṣíṣe ohun tí ó tọ́ sàn ju ẹbọ lọ (3) Iṣẹ́ àṣekára máa ń múni ṣàṣeyọrí (5) Ẹni tí kì í fetí sí ẹni rírẹlẹ̀, a ò ní gbọ́ tiẹ̀ (13) Kò sí ọgbọ́n tó lòdì sí Jèhófà tó lè dúró (30) 22 Orúkọ rere sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ (1) Kíkọ́ ọmọ láti kékeré máa ṣe é láǹfààní jálẹ̀ ayé rẹ̀ (6) Ọ̀lẹ ń bẹ̀rù kìnnìún tó wà níta (13) Ìbáwí ń mú ìwà òmùgọ̀ kúrò (15) Òṣìṣẹ́ tó bá já fáfá ló ń bá àwọn ọba ṣiṣẹ́ (29) 23 Máa lo làákàyè tí wọ́n bá ń ṣe ọ́ lálejò (2) Má ṣe máa lé ọrọ̀ (4) Ọrọ̀ lè fò lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ (5) Má ṣe wà lára àwọn tó ń mutí lámujù (20) Ọtí máa ń buni ṣán bí ejò (32) 24 Má ṣe jowú àwọn ẹni ibi (1) Ọgbọ́n ni a fi ń gbé ilé ró (3) Olódodo lè ṣubú, àmọ́ yóò dìde (16) Má gbẹ̀san (29) Ìtòògbé ń sọni di òtòṣì (33, 34) ÀWỌN ÒWE SÓLÓMỌ́NÌ TÍ ÀWỌN ỌKÙNRIN ỌBA HẸSIKÁYÀ DÀ KỌ (25:1–29:27) 25 Pípa àṣírí mọ́ (9) Ọ̀rọ̀ téèyàn rò dáadáa kó tó sọ (11) Má tojú bọ ilé onílé (17) Kíkó ẹyin iná lé ọ̀tá lórí (21, 22) Ìròyìn rere dà bí omi tútù (25) 26 Ìwà àwọn ọ̀lẹ (13-16) Má ṣe dá sí ìjà tí kì í ṣe tìrẹ (17) Yẹra fún dídá àpárá (18, 19) Kò sígi, kò síná (20, 21) Ọ̀rọ̀ abanijẹ́ dà bí òkèlè dídùn (22) 27 Ìbáwí látọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń ṣeni láǹfààní (5, 6) Ọmọ mi, mú ọkàn mi yọ̀ (11) Irin ń pọ́n irin (17) Mọ agbo ẹran rẹ (23) Ọrọ̀ kì í wà títí láé (24) 28 Àdúrà ẹni tí kò pa òfin mọ́ jẹ́ ohun ìríra (9) Ẹni tó bá jẹ́wọ́ á rí àánú gbà (13) Èèyàn ò lè kánjú di ọlọ́rọ̀ láì jẹ̀bi (20) Ká báni wí sàn ju ká máa pọ́nni (23) Ẹni tó lawọ́ kò ní ṣaláìní (27) 29 Ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ máa ń kó ìtìjú báni (15) Láìsí ìran, àwọn èèyàn á ya ìyàkuyà (18) Ẹni tó ń bínú máa ń dá wàhálà sílẹ̀ (22) Onírẹ̀lẹ̀ máa ń gba ògo (23) Ìbẹ̀rù èèyàn jẹ́ ìdẹkùn (25) 30 ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ ÁGÚRÌ (1-33) Má ṣe fún mi ní òṣì tàbí ọrọ̀ (8) Àwọn ohun tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn (15, 16) Àwọn ohun tí èèyàn kò lè tọ ipasẹ̀ rẹ̀ (18, 19) Obìnrin alágbèrè (20) Àwọn ẹranko tó ní ọgbọ́n àdámọ́ni (24) 31 ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ ỌBA LÉMÚẸ́LÌ (1-31) Tá ló ti rí aya tó dáńgájíà? (10) Ẹni tí kì í ṣọ̀lẹ àti òṣìṣẹ́ kára (17) Òfin inú rere wà ní ahọ́n rẹ̀ (26) Ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ yìn ín (28) Òòfà ẹwà àti ẹwà ojú kì í tọ́jọ́ (30)