Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Émọ́sì ÉMỌ́SÌ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Émọ́sì gba iṣẹ́ kan látọ̀dọ̀ Jèhófà (1, 2) Ìdájọ́ lórí ìdìtẹ̀ tó ń wáyé (3-15) Síríà (3-5), Filísíà (6-8), Tírè (9, 10), Édómù (11, 12), Ámónì (13-15) 2 Ìdájọ́ lórí ìdìtẹ̀ tó ń wáyé (1-16) Móábù (1-3), Júdà (4, 5), Ísírẹ́lì (6-16) 3 Ìkéde ìdájọ́ Ọlọ́run (1-8) Ọlọ́run ń fi àṣírí ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn (7) Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Samáríà (9-15) 4 Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn abo màlúù Báṣánì (1-3) Jèhófà kórìíra ìjọsìn èké Ísírẹ́lì (4, 5) Ísírẹ́lì kò gba ìbáwí (6-13) “Múra sílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run rẹ” (12) ‘Ọlọ́run ń sọ èrò rẹ̀ fún àwọn èèyàn’ (13) 5 Ísírẹ́lì dà bíi wúńdíá tó ṣubú (1-3) Wá Ọlọ́run, kí o lè máa wà láàyè (4-17) Kórìíra ohun búburú, nífẹ̀ẹ́ ohun rere (15) Ọjọ́ Jèhófà máa jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn (18-27) Ọlọ́run kọ ẹbọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (22) 6 Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ kò mikàn (1-14) Ibùsùn tí wọ́n fi eyín erin ṣe; abọ́ wáìnì (4, 6) 7 Ìran tó fi hàn pé òpin Ísírẹ́lì ti sún mọ́lé (1-9) Eéṣú (1-3), iná (4-6), okùn ìwọ̀n (7-9) Wọ́n ní kí Émọ́sì má sọ tẹ́lẹ̀ mọ́ (10-17) 8 Ìran apẹ̀rẹ̀ tí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn wà nínú rẹ̀ (1-3) Ọlọ́run dẹ́bi fún àwọn aninilára (4-14) Ìyàn tẹ̀mí (11) 9 Ìdájọ́ Ọlọ́run kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ (1-10) Ọlọ́run á gbé àtíbàbà Dáfídì dìde (11-15)