Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Málákì MÁLÁKÌ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ (1-5) Àwọn àlùfáà ń fi ẹran tó lábùkù rúbọ (6-14) Wọ́n á gbé orúkọ Ọlọ́run ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè (11) 2 Àwọn àlùfáà ò kọ́ àwọn èèyàn (1-9) Ó yẹ kí ìmọ̀ máa wà ní ètè àwọn àlùfáà (7) Àwọn èèyàn jẹ̀bi ìkọ̀sílẹ̀ tí kò tọ́ (10-17) “‘Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀,’ ni Jèhófà” wí (16) 3 Olúwa tòótọ́ wá fọ tẹ́ńpìlì rẹ̀ mọ́ (1-5) Ìránṣẹ́ májẹ̀mú náà (1) Jèhófà rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ òun (6-12) Jèhófà kì í yí pa dà (6) “Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì pa dà sọ́dọ̀ yín” (7) ‘Ẹ mú gbogbo ìdá mẹ́wàá wá, Jèhófà yóò sì tú ìbùkún sórí yín’ (10) Olódodo àti ẹni burúkú (13-18) Wọ́n kọ ìwé ìrántí kan níwájú Ọlọ́run (16) Ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú (18) 4 Èlíjà yóò wá kí ọjọ́ Jèhófà tó dé (1-6) “Oòrùn òdodo yóò ràn” (2)