LÚÙKÙ
OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ
-
Jésù ni “Olúwa Sábáàtì” (1-5)
Ó wo ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ rọ sàn (6-11)
Àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12-16)
Jésù ń kọ́ni, ó sì ń woni sàn (17-19)
Àwọn aláyọ̀ àtàwọn tí a káàánú wọn (20-26)
Nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá (27-36)
Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́ mọ́ (37-42)
Èso igi la fi ń mọ̀ ọ́n (43-45)
Ilé tí wọ́n kọ́ dáadáa; ilé tí ìpìlẹ̀ rẹ̀ ò lágbára (46-49)
-
Àwọn obìnrin tó ń tẹ̀ lé Jésù (1-3)
Àpèjúwe afúnrúgbìn (4-8)
Ìdí tí Jésù fi ń lo àwọn àpèjúwe (9, 10)
Ó ṣàlàyé àpèjúwe afúnrúgbìn (11-15)
A kì í bo fìtílà mọ́lẹ̀ (16-18)
Ìyá Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ (19-21)
Jésù mú kí ìjì dáwọ́ dúró (22-25)
Jésù lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde sínú ẹlẹ́dẹ̀ (26-39)
Ọmọbìnrin Jáírù; obìnrin kan fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè Jésù (40-56)
-
Ó fún àwọn Méjìlá náà ní ìtọ́ni nípa iṣẹ́ ìwàásù (1-6)
Ìdààmú bá Hẹ́rọ́dù torí Jésù (7-9)
Jésù bọ́ 5,000 èèyàn (10-17)
Pétérù pè é ní Kristi (18-20)
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú Jésù (21, 22)
Ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn (23-27)
A yí Jésù pa dà di ológo (28-36)
Ó wo ọmọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu sàn (37-43a)
Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ (43b-45)
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù (46-48)
Ẹni tí kò bá ta kò wá, tiwa ló ń ṣe (49, 50)
Àwọn ará abúlé kan ní Samáríà kọ Jésù (51-56)
Bí a ṣe lè tẹ̀ lé Jésù (57-62)
-
Ìwúkàrà àwọn Farisí (1-3)
Bẹ̀rù Ọlọ́run, má bẹ̀rù èèyàn (4-7)
Fi hàn pé o wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi (8-12)
Àpèjúwe ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó jẹ́ òmùgọ̀ (13-21)
Ẹ yéé ṣàníyàn (22-34)
Agbo kékeré (32)
Ṣíṣọ́nà (35-40)
Ìríjú olóòótọ́ àti ìríjú aláìṣòótọ́ (41-48)
Kì í ṣe àlàáfíà, ìpínyà ni (49-53)
Ó yẹ kí wọ́n ṣàyẹ̀wò àkókò (54-56)
Yíyanjú ọ̀rọ̀ (57-59)
-
Àwọn àlùfáà gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù (1-6)
Wọ́n múra Ìrékọjá tó gbẹ̀yìn sílẹ̀ (7-13)
Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀ (14-20)
“Èmi àti ẹni tó máa dà mí jọ wà lórí tábìlì” (21-23)
Wọ́n bára wọn jiyàn gidigidi nípa ẹni tó tóbi jù (24-27)
Jésù bá wọn dá májẹ̀mú ìjọba (28-30)
Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Pétérù máa sẹ́ òun (31-34)
Ìdí tó fi yẹ kí wọ́n múra sílẹ̀; idà méjì (35-38)
Àdúrà Jésù lórí Òkè Ólífì (39-46)
Wọ́n mú Jésù (47-53)
Pétérù sẹ́ Jésù (54-62)
Wọ́n fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́ (63-65)
Wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (66-71)