Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìṣe ÌṢE ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ó kọ̀wé sí Tìófílọ́sì (1-5) Iṣẹ́ ìwàásù máa dé gbogbo ìkángun ayé (6-8) Jésù gòkè lọ sọ́run (9-11) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn kóra jọ ní ìṣọ̀kan (12-14) Wọ́n yan Màtáyásì rọ́pò Júdásì (15-26) 2 Ẹ̀mí mímọ́ tú jáde ní Pẹ́ńtíkọ́sì (1-13) Ọ̀rọ̀ Pétérù (14-36) Ọ̀pọ̀ èèyàn gba ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ (37-41) Èèyàn 3,000 ṣèrìbọmi (41) Ìbákẹ́gbẹ́ Kristẹni (42-47) 3 Pétérù wo arọ tó ń tọrọ nǹkan sàn (1-10) Ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Sólómọ́nì (11-26) ‘Ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo’ (21) Wòlíì kan bíi Mósè (22) 4 Wọ́n mú Pétérù àti Jòhánù (1-4) Iye àwọn onígbàgbọ́ di 5,000 ọkùnrin (4) Ìgbẹ́jọ́ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (5-22) ‘A ò lè ṣàì sọ̀rọ̀’ (20) Àdúrà ìgboyà (23-31) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ pín ohun tí wọ́n ní (32-37) 5 Ananáyà àti Sàfírà (1-11) Àwọn àpọ́sítélì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì (12-16) Wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì dá wọn sílẹ̀ (17-21a) Wọ́n tún mú wọn wá síwájú Sàhẹ́ndìrìn (21b-32) ‘Ṣègbọràn sí Ọlọ́run dípò èèyàn’ (29) Ìmọ̀ràn Gàmálíẹ́lì (33-40) Wọ́n ń wàásù láti ilé dé ilé (41, 42) 6 Wọ́n yan ọkùnrin méje láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ (1-7) Wọ́n fẹ̀sùn kan Sítéfánù pé ó sọ̀rọ̀ òdì (8-15) 7 Ọ̀rọ̀ tí Sítéfánù sọ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (1-53) Ìgbà ayé àwọn baba ńlá (2-16) Mósè ṣe aṣáájú; Ísírẹ́lì bọ̀rìṣà (17-43) Ọlọ́run kì í gbé inú tẹ́ńpìlì tí èèyàn kọ́ (44-50) Wọ́n sọ Sítéfánù lókùúta (54-60) 8 Sọ́ọ̀lù ṣe inúnibíni (1-3) Ìwàásù Fílípì sèso rere ní Samáríà (4-13) Wọ́n rán Pétérù àti Jòhánù lọ sí Samáríà (14-17) Símónì fẹ́ ra ẹ̀mí mímọ́ (18-25) Ìwẹ̀fà ará Etiópíà (26-40) 9 Sọ́ọ̀lù wà ní ọ̀nà Damásíkù (1-9) Olúwa rán Ananáyà pé kó lọ ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́ (10-19a) Sọ́ọ̀lù wàásù nípa Jésù ní Damásíkù (19b-25) Sọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálẹ́mù (26-31) Pétérù wo Énéà sàn (32-35) Dọ́káàsì tó jẹ́ ọ̀làwọ́ jíǹde (36-43) 10 Ìran tí Kọ̀nílíù rí (1-8) Pétérù rí àwọn ẹranko tí a ti sọ di mímọ́ nínú ìran (9-16) Pétérù wá sílé Kọ̀nílíù (17-33) Pétérù kéde ìhìn rere fún àwọn Kèfèrí (34-43) “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú” (34, 35) Àwọn Kèfèrí gba ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi (44-48) 11 Pétérù ròyìn fún àwọn àpọ́sítélì (1-18) Bánábà àti Sọ́ọ̀lù wà ní Áńtíókù ti Síríà (19-26) Ìgbà àkọ́kọ́ tí a pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni (26) Ágábù sọ tẹ́lẹ̀ pé ìyàn máa mú (27-30) 12 Wọ́n pa Jémíìsì; wọ́n fi Pétérù sẹ́wọ̀n (1-5) Ọlọ́run dá Pétérù sílẹ̀ lọ́nà ìyanu (6-19) Áńgẹ́lì kọ lu Hẹ́rọ́dù (20-25) 13 Wọ́n rán Bánábà àti Sọ́ọ̀lù láti lọ ṣe míṣọ́nnárì (1-3) Iṣẹ́ ìwàásù ní Sápírọ́sì (4-12) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ní Áńtíókù ti Písídíà (13-41) Àsọtẹ́lẹ̀ tó fún wọn láṣẹ láti yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè (42-52) 14 Ní Íkóníónì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, inúnibíni sì ń ṣẹlẹ̀ (1-7) Ní Lísírà, wọ́n rò pé ọlọ́run ni wọ́n (8-18) Wọ́n sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta, àmọ́ kò kú (19, 20) Wọ́n ń fún àwọn ìjọ lókun (21-23) Wọ́n pa dà sí Áńtíókù ti Síríà (24-28) 15 Awuyewuye ní Áńtíókù lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ (1, 2) Wọ́n gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí Jerúsálẹ́mù (3-5) Àwọn alàgbà àti àwọn àpọ́sítélì ṣèpàdé (6-21) Lẹ́tà látọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ olùdarí (22-29) Ta kété sí ẹ̀jẹ̀ (28, 29) Lẹ́tà náà gbé àwọn ìjọ ró (30-35) Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lọ ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ (36-41) 16 Pọ́ọ̀lù mú Tímótì (1-5) Ìran ọkùnrin ará Makedóníà (6-10) Lìdíà di onígbàgbọ́ ní ìlú Fílípì (11-15) Wọ́n ju Pọ́ọ̀lù àti Sílà sẹ́wọ̀n (16-24) Ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti agbo ilé rẹ̀ ṣèrìbọmi (25-34) Pọ́ọ̀lù ní kí àwọn aláṣẹ wá tọrọ àforíjì (35-40) 17 Pọ́ọ̀lù àti Sílà ní Tẹsalóníkà (1-9) Pọ́ọ̀lù àti Sílà ní Bèróà (10-15) Pọ́ọ̀lù ní Áténì (16-22a) Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ní Áréópágù (22b-34) 18 Iṣẹ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù ní Kọ́ríńtì (1-17) Ó pa dà sí Áńtíókù ti Síríà (18-22) Pọ́ọ̀lù lọ sí Gálátíà àti Fíríjíà (23) Àpólò tó jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ rí ìrànlọ́wọ́ gbà (24-28) 19 Pọ́ọ̀lù ní Éfésù; àwọn kan tún batisí ṣe (1-7) Àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe láti kọ́ni (8-10) Ó ń ṣàṣeyọrí láìka àwọn tó ní ẹ̀mí èṣù sí (11-20) Éfésù dà rú (21-41) 20 Pọ́ọ̀lù ní Makedóníà àti ilẹ̀ Gíríìsì (1-6) Yútíkọ́sì jíǹde ní Tíróásì (7-12) Láti Tíróásì sí Mílétù (13-16) Pọ́ọ̀lù bá àwọn alàgbà Éfésù ṣèpàdé (17-38) Ó ń kọ́ni láti ilé dé ilé (20) “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni” (35) 21 Lójú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù (1-14) Wọ́n dé Jerúsálẹ́mù (15-19) Pọ́ọ̀lù tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn alàgbà (20-26) Inú tẹ́ńpìlì dà rú; wọ́n mú Pọ́ọ̀lù (27-36) Wọ́n gba Pọ́ọ̀lù láyè kó bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀ (37-40) 22 Pọ́ọ̀lù gbèjà ara rẹ̀ níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn (1-21) Pọ́ọ̀lù lo ẹ̀tọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù tó ní (22-29) Sàhẹ́ndìrìn pé jọ (30) 23 Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (1-10) Olúwa fún Pọ́ọ̀lù lókun (11) Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Pọ́ọ̀lù (12-22) Wọ́n gbé Pọ́ọ̀lù lọ sí Kesaríà (23-35) 24 Wọ́n fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù (1-9) Pọ́ọ̀lù gbèjà ara rẹ̀ níwájú Fẹ́líìsì (10-21) Wọ́n dá ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù dúró fún ọdún méjì (22-27) 25 Pọ́ọ̀lù jẹ́jọ́ níwájú Fẹ́sítọ́ọ̀sì (1-12) “Mo ké gbàjarè sí Késárì!” (11) Fẹ́sítọ́ọ̀sì fọ̀rọ̀ lọ Ọba Ágírípà (13-22) Pọ́ọ̀lù dúró níwájú Ágírípà (23-27) 26 Pọ́ọ̀lù gbèjà ara rẹ̀ níwájú Ágírípà (1-11) Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bó ṣe yí pa dà (12-23) Èsì Fẹ́sítọ́ọ̀sì àti ti Ágírípà (24-32) 27 Pọ́ọ̀lù wọkọ̀ òkun lọ sí Róòmù (1-12) Ìjì kọ lu ọkọ̀ òkun (13-38) Ọkọ̀ òkun fọ́ (39-44) 28 Wọ́n gúnlẹ̀ sí Málítà (1-6) Bàbá Púbílọ́sì rí ìwòsàn (7-10) Wọ́n forí lé Róòmù (11-16) Pọ́ọ̀lù bá àwọn Júù sọ̀rọ̀ ní Róòmù (17-29) Pọ́ọ̀lù fi ìgboyà wàásù fún ọdún méjì (30, 31)