Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Kọ́ríńtì 1 KỌ́RÍŃTÌ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ìkíni (1-3) Pọ́ọ̀lù dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí àwọn ará Kọ́ríńtì (4-9) Ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n wà níṣọ̀kan (10-17) Kristi, agbára àti ọgbọ́n Ọlọ́run (18-25) Ẹ máa yangàn nínú Jèhófà nìkan (26-31) 2 Iṣẹ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù ní Kọ́ríńtì (1-5) Ọgbọ́n Ọlọ́run ju ti èèyàn lọ (6-10) Ẹni tara àti ẹni tẹ̀mí (11-16) 3 Àwọn ará Kọ́ríńtì ṣì jẹ́ ẹni tara (1-4) Ọlọ́run ń mú kó dàgbà (5-9) Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run (9) Fi ohun tí kò lè jóná kọ́lé (10-15) Ẹ̀yin ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run (16, 17) Ọgbọ́n ayé jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run (18-23) 4 Ó yẹ kí ìríjú jẹ́ olóòótọ́ (1-5) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ tó jẹ́ Kristẹni (6-13) ‘Má ṣe kọjá ohun tó wà lákọsílẹ̀’ (6) Àwọn Kristẹni jẹ́ ìran àpéwò (9) Pọ́ọ̀lù ń bójú tó àwọn tó jẹ́ ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí (14-21) 5 Ẹjọ́ ìṣekúṣe tó wáyé (1-5) Ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú (6-8) Ẹ mú ẹni burúkú náà kúrò (9-13) 6 Àwọn ará ń gbéra wọn lọ sílé ẹjọ́ (1-8) Àwọn tí kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run (9-11) Ẹ máa yin Ọlọ́run lógo nínú ara yín (12-20) “Ẹ máa sá fún ìṣekúṣe!” (18) 7 Ìmọ̀ràn fún àwọn tí kò gbéyàwó àti àwọn tó ti gbéyàwó (1-16) Ẹ wà ní ipò tí ẹ wà nígbà tí a pè yín (17-24) Àwọn tí kò gbéyàwó àti àwọn opó (25-40) Àǹfààní tó wà nínú kéèyàn wà láìgbéyàwó (32-35) Gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa” (39) 8 Ọ̀rọ̀ nípa oúnjẹ tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà (1-13) Ní tiwa, Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà (5, 6) 9 Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù nínú iṣẹ́ àpọ́sítélì (1-27) “O ò gbọ́dọ̀ di ẹnu akọ màlúù” (9) ‘Mo gbé tí mi ò bá wàásù!’ (16) Mo di ohun gbogbo fún gbogbo èèyàn (19-23) Bí a ṣe lè kíyè sára nínú eré ìje ìyè (24-27) 10 Àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ látinú ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (1-13) Àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ nípa ìbọ̀rìṣà (14-22) Tábìlì Jèhófà àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù (21) Òmìnira àti gbígba tàwọn ẹlòmíì rò (23-33) “Ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run” (31) 11 “Ẹ máa fara wé mi” (1) Ipò orí àti bíbo orí (2-16) Ṣíṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa (17-34) 12 Ẹ̀bùn ti ẹ̀mí (1-11) Ara kan, ẹ̀yà ara púpọ̀ (12-31) 13 Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀nà tó ta yọ (1-13) 14 Àwọn ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ àti èdè àjèjì (1-25) Àwọn ìjọ Kristẹni tó wà létòlétò (26-40) Àyè àwọn obìnrin nínú ìjọ (34, 35) 15 Àjíǹde Kristi (1-11) Àjíǹde jẹ́ ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ (12-19) Àjíǹde Kristi jẹ́ àmì ìdánilójú (20-34) Ara ìyára àti ara tẹ̀mí (35-49) Àìkú àti àìdíbàjẹ́ (50-57) Ẹ ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa (58) 16 Wọ́n kó nǹkan jọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù (1-4) Ètò ìrìn àjò Pọ́ọ̀lù (5-9) Ó ṣètò bí Tímótì àti Àpólò ṣe máa bẹ àwọn ará wò (10-12) Ọ̀rọ̀ ìyànjú àti ìkíni (13-24)