Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Gálátíà GÁLÁTÍÀ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ìkíni (1-5) Kò sí ìhìn rere míì (6-9) Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìhìn rere tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù ti wá (10-12) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe yí pa dà àti àwọn ohun tó kọ́kọ́ ṣe (13-24) 2 Pọ́ọ̀lù lọ bá àwọn àpọ́sítélì ní Jerúsálẹ́mù (1-10) Pọ́ọ̀lù bá Pétérù (Kéfà) wí (11-14) A pè wá ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ (15-21) 3 Àwọn iṣẹ́ Òfin àti ìgbàgbọ́ (1-14) Ìgbàgbọ́ yóò mú kí olódodo wà láàyè (11) Ìlérí Ọlọ́run fún Ábúráhámù kì í ṣe nípasẹ̀ Òfin (15-18) Kristi, ọmọ Ábúráhámù (16) Ibi tí Òfin ti wá àti ohun tó wà fún (19-25) Àwọn ọmọ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ (26-29) Àwọn tó jẹ́ ti Kristi jẹ́ ọmọ Ábúráhámù (29) 4 Ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́, ọmọ ni yín (1-7) Ọ̀rọ̀ àwọn ará Gálátíà jẹ Pọ́ọ̀lù lógún (8-20) Hágárì àti Sérà: májẹ̀mú méjì (21-31) Jerúsálẹ́mù ti òkè ní òmìnira, òun sì ni ìyá wa (26) 5 Òmìnira Kristẹni (1-15) Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí (16-26) Àwọn iṣẹ́ ti ara (19-21) Èso ti ẹ̀mí (22, 23) 6 Ẹ máa bá ara yín gbé ẹrù (1-10) Ohun tí èèyàn bá gbìn ló máa ká (7, 8) Ìdádọ̀dọ́ kò ṣàǹfààní (11-16) Ẹ̀dá tuntun (15) Ìparí (17, 18)