Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Fílípì FÍLÍPÌ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ìkíni (1, 2) Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run; Àdúrà Pọ́ọ̀lù (3-11) Ìhìn rere ń tẹ̀ síwájú kódà lójú wàhálà (12-20) Ààyè mi jẹ́ ti Kristi, ikú mi jẹ́ èrè (21-26) Ẹ máa hùwà lọ́nà tó yẹ ìhìn rere (27-30) 2 Ìrẹ̀lẹ̀ Kristẹni (1-4) Ìrẹ̀lẹ̀ Kristi àti ìgbéga rẹ̀ (5-11) Ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí (12-18) Ẹ máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ (15) Ó rán Tímótì àti Ẹpafíródítù (19-30) 3 Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ẹran ara (1-11) Ohun gbogbo jẹ́ àdánù nítorí Kristi (7-9) Mò ń nàgà láti gba èrè náà (12-21) Ìlú ìbílẹ̀ wa wà ní ọ̀run (20) 4 Ìṣọ̀kan, ayọ̀, èrò tí ó tọ́ (1-9) Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun (6, 7) Pọ́ọ̀lù mọyì ẹ̀bùn àwọn ará Fílípì (10-20) Ìkíni tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (21-23)