Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Hébérù HÉBÉRÙ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ (1-4) Ọmọ ju àwọn áńgẹ́lì lọ (5-14) 2 Ká túbọ̀ máa fiyè sí àwọn ohun tí a gbọ́ (1-4) A fi ohun gbogbo sábẹ́ Jésù (5-9) Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ (10-18) Olórí Aṣojú ìgbàlà wọn (10) Àlùfáà àgbà tó jẹ́ aláàánú (17) 3 Jésù ju Mósè lọ (1-6) Ọlọ́run ló kọ́ ohun gbogbo (4) Ìkìlọ̀ nípa àìnígbàgbọ́ (7-19) “Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀” (7, 15) 4 Ohun tí kò jẹ́ kí wọ́n wọnú ìsinmi Ọlọ́run (1-10) Ká sapá ká lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run (11-13) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè (12) Jésù, àlùfáà àgbà tó tóbi (14-16) 5 Jésù tóbi ju àwọn èèyàn tó jẹ́ àlùfáà àgbà lọ (1-10) Ní ọ̀nà ti Melikisédékì (6, 10) Ó kọ́ ìgbọràn látinú ìyà tó jẹ (8) A máa ní ìgbàlà àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ rẹ̀ (9) Ìkìlọ̀ nípa àìdàgbà nípa tẹ̀mí (11-14) 6 Ká tẹ̀ síwájú, ká sì dàgbà nípa tẹ̀mí (1-3) Àwọn tó yẹsẹ̀ tún kan Ọmọ mọ́gi (4-8) Ẹ jẹ́ kí ìrètí yín dá yín lójú (9-12) Ìlérí Ọlọ́run dájú (13-20) Ìlérí Ọlọ́run àti ohun tó búra ò lè yí pa dà (17, 18) 7 Melikisédékì, ọba àti àlùfáà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ (1-10) Bí Jésù ṣe jẹ́ àlùfáà tó tóbi jù (11-28) Kristi lè gbani là pátápátá (25) 8 Àgọ́ ìjọsìn tó jẹ mọ́ nǹkan ti ọ̀run (1-6) Ìyàtọ̀ tó wà láàárín májẹ̀mú ti tẹ́lẹ̀ àti májẹ̀mú tuntun (7-13) 9 Ìjọsìn mímọ́ ní ibi mímọ́ tó wà láyé (1-10) Kristi wọ ọ̀run pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ (11-28) Alárinà májẹ̀mú tuntun (15) 10 Fífi ẹran rúbọ ò gbéṣẹ́ (1-4) Òfin jẹ́ òjìji (1) Kristi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé (5-18) Ọ̀nà àbáwọlé tuntun tó jẹ́ ọ̀nà ìyè (19-25) Ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀ (24, 25) Ìkìlọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí a mọ̀ọ́mọ̀ dá (26-31) Ìgboyà àti ìgbàgbọ́ máa jẹ́ ká lè fara dà á (32-39) 11 Ohun tí ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí (1, 2) Àwọn àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ (3-40) Kò ṣeé ṣe láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa láìsí ìgbàgbọ́ (6) 12 Jésù ni Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa (1-3) Àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí (1) Má fojú kéré ìbáwí látọ̀dọ̀ Jèhófà (4-11) Ẹ ṣe ọ̀nà tó tọ́ fún ẹsẹ̀ yín (12-17) Wọ́n sún mọ́ Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run (18-29) 13 Ọ̀rọ̀ ìyànjú àti ìkíni tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (1-25) Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe aájò àlejò (2) Kí ìgbéyàwó ní ọlá (4) Ẹ máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú (7, 17) Ẹ máa rú ẹbọ ìyìn (15, 16)