Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Pétérù 1 PÉTÉRÙ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ìkíni (1, 2) Ìbí tuntun tó jẹ́ ká lè ní ìrètí tó wà láàyè (3-12) Ẹ jẹ́ mímọ́ bí ọmọ tó ń ṣègbọràn (13-25) 2 Kí ọ̀rọ̀ náà máa wù yín (1-3) Òkúta ààyè tí a fi kọ́ ilé tẹ̀mí (4-10) Ẹ máa gbé bí àjèjì nínú ayé (11, 12) Àwọn tó yẹ ká tẹrí ba fún (13-25) Kristi fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa (21) 3 Àwọn ọkọ àti àwọn aya (1-7) Ẹ máa bára yín kẹ́dùn; ẹ máa wá àlàáfíà (8-12) Tí a bá ń jìyà nítorí òdodo (13-22) Ẹ ṣe tán láti gbèjà ìrètí yín (15) Ìrìbọmi àti ẹ̀rí ọkàn rere (21) 4 Ẹ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bíi ti Kristi (1-6) Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé (7-11) Tí a bá ń jìyà torí pé a jẹ́ Kristẹni (12-19) 5 Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run (1-4) Ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí ẹ sì wà lójúfò (5-11) Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé Ọlọ́run (7) Èṣù dà bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù (8) Ọ̀rọ̀ ìparí (12-14)