Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Jòhánù 1 JÒHÁNÙ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ọ̀rọ̀ ìyè (1-4) Ká máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ (5-7) Ìdí tó fi yẹ ká máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa (8-10) 2 Ó fi Jésù ṣe ẹbọ ìpẹ̀tù (1, 2) Ká máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ (3-11) Àṣẹ àtijọ́ àti àṣẹ tuntun (7, 8) Ìdí tó fi kọ̀wé sí wọn (12-14) Ẹ má ṣe nífẹ̀ẹ́ ayé (15-17) Ìkìlọ̀ nípa aṣòdì sí Kristi (18-29) 3 Ọmọ Ọlọ́run ni wá (1-3) Àwọn ọmọ Ọlọ́run yàtọ̀ sí àwọn ọmọ Èṣù (4-12) Jésù máa fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú (8) Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín (13-18) Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ (19-24) 4 Ẹ dán àwọn ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí wò (1-6) Ẹ mọ Ọlọ́run, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ (7-21) “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́” (8, 16) Kò sí ìbẹ̀rù nínú ìfẹ́ (18) 5 Ẹni tó bá gba Jésù gbọ́ ti ṣẹ́gun ayé (1-12) Ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí (3) Ohun tó dá wa lójú nípa agbára tí àdúrà ní (13-17) Ẹ máa ṣọ́ra nínú ayé tó burú (18-21) Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà (19)