Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti Àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ ITALI
ÀKỌLÉ ìgbàanì kan tí a rí ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Romu, Itali, lè fìdí ẹ̀rí àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli kan múlẹ̀ nípa ìparun Jerusalemu láìṣe tààràtà. Ó dájú pé àkọlé náà ní ohun kan láti ṣe pẹ̀lú kíkọ́ àti ṣíṣí Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà ní ọdún 80 Sànmánì Tiwa. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Géza Alföldy ti Yunifásítì Heidelberg, Germany, ti ṣàtúnkọ rẹ̀, àkọlé náà kà pé: “Olú Ọba Titu Vespasian Kesari Augustu sọ pé kí a tún gbọ̀ngàn tuntun náà kọ́ pẹ̀lú àwọn ohun tí a piyẹ́.” Ohun ìpiyẹ́ wo?
Alföldy sọ pé: “A ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun ìpiyẹ́ jaburata tí Titu kó nínú ogun tí a bá àwọn Júù jà, àti ní pàtàkì, àwọn ohun ọ̀ṣọ́ oníwúrà” inú tẹ́ḿpìlì ní Jerusalemu. Wọ́n pa tẹ́ḿpìlì yìí run ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jesu. (Matteu 24:1, 2; Luku 21:5, 6) Alföldy parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà—papọ̀ pẹ̀lú Ọwọ̀n Bìrìkìtì Titu tí ó lókìkí náà, tí ó ṣàpèjúwe àwọn aṣẹ́gun láti Romu tí wọ́n di àwọn ohun ìpiyẹ́ tí wọ́n kó nínú ogun àwọn Júù—jẹ́ ohun ìrántí nínú ìṣẹ́gun onítàn àwọn ará Romu náà.