Yímíyímí Ilẹ̀ Áfíríkà Yanjú Ọ̀ràn Náà!
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ
NÍ Ọ̀RÚNDÚN méjì sẹ́yìn, nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ kó màlúù dé Australia, ta ló mọ̀ pé ó lè yọrí sí ìṣòro lílé kenkà fún orílẹ̀-èdè náà?
Bí àkókò ti ń lọ, ẹlẹ́bọ́tọ bo gbogbo pápá pelemọ, kò sì jẹ́ kí koríko hù ní àwọn ibì kan tàbí kí ó tilẹ̀ máà jẹ́ kí àwọn koríkò náà ṣeé jẹ fún àwọn màlúù. Àwọn òkìtì ẹlẹ́bọ́tọ náà wá di ilé ìpamọ gbígbórín kan fún àwọn kòkòrò tí ń múnú bíni. Kí tilẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìròyìn ìwé agbéròyìnjáde Africa—Environment & Wildlife sọ, nígbà tí yóò fi di àwọn ọdún 1970, ìṣòro náà ti dé “ìwọ̀n gígogò ní ti ọrọ̀ ajé àti ti ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti ibùgbé wọn.” Wọ́n ṣírò rẹ̀ pé “ohun tí ó ju mílíọ̀nù méjì hẹ́kítà [mílíọ̀nù márùn-ún eékà] pápá ni nǹkankan kì í hù níbẹ̀ mọ́ lọ́dọọdún . . . , ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èròjà nitrogen ni kò padà lọ sínú ilẹ̀ mọ́ nítorí ẹlẹ́bọ́tọ tí kò wọnú ilẹ̀, iye àwọn kòkòrò sì ń pọ̀ sí i lọ́nà tí ó gọntiọ.”
Kí ló ṣẹlẹ̀? Ní Áfíríkà, àwọn yímíyímí ní tiwọn ni wọ́n máa ń palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ kúrò lórí pápá ní wàràǹwéré àti ní tónítóní. Ẹlẹ́bọ́tọ tí wọ́n bá rì mọ́lẹ̀ yóò mú kí ilẹ̀ náà ní ajílẹ̀, yóò sì mú kí ó tú yẹ́ríyẹ́rí, tí èyí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àwọn ewéko hù dáradára sí i. Lọ́nà yìí, wọn yóò ṣàkóso àwọn irú ẹ̀yà kòkòrò tí wọ́n lè pani lára, wọ́n yóò sì run àwọn ẹyin kòkòrò àrùn, èyí sì ń ṣèdíwọ́ fún ìtànkálẹ̀ àwọn àrùn tí kòkòrò ń fà.
Bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí àwọn tí ó kọ́kọ́ ń gbé ní Australia kò mọ̀ ni pé àwọn yímíyímí Australia máa ń ṣíṣẹ́ lórí àwọn ìgbẹ́ kondo kondo kéékèèké líle, tí àwọn ẹranko tí ó jẹ́ ti ilẹ̀ náà bá yà, wọn kò sì lè ṣe ohunkóhun lórí àwọn ẹbọ́tọ ìgbẹ́ bàràkàtà bàràkàtà ti màlúù.
Kí ni wọn yóò wá ṣe báyìí? Kí wọn kó àwọn yímíyímí wọlé láti àwọn orílẹ̀-èdè míràn ló kù! Fún àpẹẹrẹ, irú èyí tí ó wà ní ilẹ̀ Áfíríkà, (èyí tí irú ẹ̀yà rẹ̀ jẹ́ nǹkan bíi 2,000), máa ń ṣe ribiribi lórí ọ̀pọ̀ yanturu ẹbọ́tọ ìgbẹ́, irú bí èyí tí àwọn erin máa ń yà yẹn. Fún àwọn yímíyímí wọ̀nyí, ṣíṣaáyan ìgbẹ́ pẹẹli pẹẹli àwọn màlúù kì í ṣe ìṣòro pẹ́ẹ̀pẹ́ẹ̀. Àmọ́, ẹ wo bí iye yímíyímí tí wọn yóò nílò láti ṣe iṣẹ́ náà yóò ti pọ̀ tó! Ìwé ìròyìn Africa—Environment & Wildlife ròyìn pé, ní ọgbà ìtura kan, “wọ́n rí 7 000 yímíyímí níbi òkìtì ìgbẹ́ kan ṣoṣo tí ó jẹ́ ti ìgbẹ́ erin,” ní ọgbà ìtura mìíràn, “wọ́n fi wákàtí 12 kó yímíyímí 22 746 . . . níbi òkìtì ìgbẹ́ erin tí ó jẹ́ kìlógíráàmù 7 [15 lb].” Ìwọ náà fojú inú wo ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ iye yímíyímí tí wọn yóò nílò láti yanjú ìṣòro àjálù ti Australia!
Ó dùn mọ́ni pé, ìṣòro náà ti ń yanjú dáadáa ní lọ́ọ́lọ́ọ́ báyìí—ọpẹ́lọpẹ́ àwọn yímíyímí ilẹ̀ Áfíríkà.