‘Ó Yẹ Kí Gbogbo Ènìyàn Tí Ó Wà Láyé Ka Ìtẹ̀jáde Yìí’
ÒǸKÀWÉ kan láti Alabama, U.S.A., fi ìmọrírì àtọkànwá hàn fún Jí!, ó sì kọ̀wé pé:
“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn Jí! àtijọ́ kan, tí ó ní àkọlé náà, “Wọn Ṣẹgun Loju Ikú” (May 8, 1993) tán ni. N kò yéé kà á. Ó kún fún ìsọfúnni, òkodoro òtítọ́, ó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.
“Mo lérò pé ó yẹ kí gbogbo ènìyàn tí ó wà láyé ka ìtẹ̀jáde yìí!”
A ń ṣe Jí! jáde ní èdè 78 láti la àwọn ẹlòmíràn lóye. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ ń jíròrò nípa ìsìn àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, àti àwọn ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, èrò ìmọ̀lára, àti ti ìdílé tí ó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ ènìyàn.
Bí o bá fẹ́ láti gba Jí! tàbí tí o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá sí ilé rẹ láti jíròrò ìníyelórí ẹ̀kọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, fún ìsọfúnni síwájú sí i, tàbí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ nínú èyí tí a tò sí ojú ewé 5.