Àìlábòsí Ló Ń Wá
Ọ̀dọ́bìnrin kan ní Ecuador lọ ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan fún iṣẹ́. Lẹ́yìn jí jíròrò pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ ń wáṣẹ́—àwọn 36 lápapọ̀—ó rí i pé ṣíṣeéṣe òun láti ríṣẹ́ náà kéré púpọ̀. Kò ní ìrírí lẹ́nu iṣẹ́ àti ẹ̀kọ́ ìwé yunifásítì tí wọ́n ní. Ó tún ṣi méjì nínú ìbéèrè mẹ́fà tí wọ́n bi í. Bí ó ti wù kí ó rí, ìbéèrè kan jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni pé: “Kí ni ọ̀rọ̀ náà, òtítọ́, túmọ̀ sí fún ọ?”
Obìnrin náà dáhùn pé: “Òtítọ́ kì í wulẹ̀ í ṣe àbá èrò orí lásán kan, ó jẹ́ ọ̀nà ìgbé ayé tí ó yẹ fúnni. A gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́ láìṣèké, nítorí bí a bá ń ṣèké, a ń tọ ipa ọ̀nà Sátánì Èṣù. Bí a bá ń sọ òtítọ́, a ń múnú Ọlọ́run dùn, a sì ń jẹ ọ̀pọ̀ àǹfààní ara ẹni.”
Nígbà tí ọ̀gá ilé iṣẹ́ náà béèrè ìsìn rẹ̀, ó dáhùn pé òún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ní ọjọ́ kejì, a fi tó o létí pé a ti gbà á síṣẹ́ náà. Oṣù kan lẹ́yìn náà, obìnrin náà bi ọ̀gá ilé iṣẹ́ náà léèrè ìdí tí ó fi gba òun síṣẹ́, ó sì sọ pé, ó jẹ́ nítorí àìlábòsí rẹ̀.
Òtítọ́ ha kọ́ ni pé ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí jẹ́ alábòsí? Ní ìdà kejì, a mọ àwọn ènìyàn tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún Bíbélì nítorí àìlábòsí wọn. Ilé-Ìṣọ́nà ti July 1, 1995, wí pé: “Nínú Bíbélì, ‘òtítọ́’ kì í ṣe èrò ìpìlẹ̀ dídíjú, tí kò já mọ́ nǹkan kan tí àwọn ọlọ́gbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn ń jiyàn lé lórí.”
Ìwọ yóò jàǹfààní láti inú kíka Ilé Ìṣọ́, tí a mọ̀ kárí ayé bí agbátẹrù òtítọ́ Bíbélì, déédéé. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ẹ̀dà kan tàbí bí o bá fẹ́ láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, fún ìsọfúnni síwájú sí i, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.