“Ìwọ Yóò Rí Ìsọfúnni Dídára Jù Bí O Bá Ń ka Jí!”
ÌYẸN ni ohun tí a sọ fún Pasquale, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí ń kẹ́kọ̀ọ́ ní kọ́lẹ́ẹ̀jì kan ní Bari, Ítálì, nígbà tí ó béèrè fún ìsọfúnni tí olùkọ́ tí ń kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìrònú òun ìhùwà ní lórí ìjoògùnyó. Síbẹ̀, olùkọ́ yìí ti máa ń fi ẹ̀tanú hàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀. Kí ló mú kí ìṣarasíhùwà rẹ̀ yí padà?
Pasquale ṣàlàyé pé: “Ní ìparí ìjókòó ìkẹ́kọ̀ọ́ kan, olùkọ́ náà sọ pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ bá a wá àwọn ìsọfúnni tí wọ́n bá lè rí nípa bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, tí ó jẹ́ kókó iṣẹ́ ìwádìí tí ó ń múra fún ẹ̀kọ́ ẹ̀yìn ìgboyèjáde kan. Mo rántí àwọn ìtẹ̀jáde Jí! mélòó kan tí ó ti sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí àti àwọn mìíràn tí wọ́n bá a tan, bí ‘Ẹ̀kọ́ Ìbálòpọ̀—Ta Ní Gbọdọ̀ Fi Kọ́ni?’ (February 22, 1992, Gẹ̀ẹ́sì). Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí pé mo mọ̀ nípa ẹ̀tanú tí olùkọ́ mi ní sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo bẹ akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ mi kan láti bá mi fún un ní àwọn ìwé ìròyìn náà.”
Pasquale ṣàpèjúwe ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó lọ béèrè lọ́wọ́ olùkọ́ rẹ̀ nípa ìsọfúnni tí ó fẹ́ẹ́ gbà lórí ìsọdibárakú oògùn líle ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà pé: “Kò dáhùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dìde dúró, ó sì wáá bọ̀ mí lọ́wọ́. Ó sọ pé òun kò ti fẹ́ẹ́ máa gba àwọn ìwé ìròyìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀ nítorí pé òún kà wọ́n sí ohun tí kò lè kọ́ni ní ohunkóhun, tí ó sì wà fún àwọn ọmọdé. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn tí ó kà wọ́n, ó yí ìrònú rẹ̀ padà. Ó sọ pé òún rí i pé àwọn ohun tí ó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà ni ó wúlò jù lọ ní ojú ìwòye àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Ó sọ pé òun yóò lo àwọn kókó ọ̀rọ̀ láti inú Jí! nínú àkọsílẹ̀ ìwádìí òun.”
Nípa ìbéèrè Pasquale fún ìsọfúnni lórí ìjoògùnyó ńkọ́? Ó dáhùn pé: “Èmi yóò fínnúfíndọ̀ fi wọ́n fún ọ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò rí ìsọfúnni dídára jù bí o bá ń ka Jí! Ó jẹ́ ìwé ìròyìn tí ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó níníye lórí, ó sì wúlò, kódà, ní ìpele ẹ̀kọ́ yunifásítì pàápàá.”
Jí! máa ń ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìṣòro lọ́ọ́lọ́ọ́, ó sì ń sapá láti pèsè ìrànwọ́ gbígbéṣẹ́ fún àwọn tí ń dojú kọ àwọn ìpèníjà ńlá tàbí kékeré nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti mọ ìrànwọ́ tí Bíbélì lè pèsè, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ń pín Jí! kiri, tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó yẹ nínú àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.