“Àṣìṣe Méje tí Àìgbọ́n Fà Láyé”
A GBỌ́ pé Mohandas Gandhi ṣàgbékalẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ohun tí ó pè ní “Àṣìṣe Méje tí Àìgbọ́n Fà Láyé.” Àwọn nìwọ̀nyí:
• Ọrọ̀ láìní iṣẹ́
• Ìgbádùn láìní ẹ̀rí ọkàn
• Ìmọ̀ láìní ìwà
• Àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà láìní ìwà rere
• Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì láìsí ìgbatẹnirò
• Ìjọsìn láìsí ìrúbọ
• Ìṣèlú láìní ìpinnu ṣíṣe ohun tó tọ́
A gbọ́ pé ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, Arun Gandhi, ló fi ìkẹjọ yìí kún un:
• Ẹ̀tọ́ láìsí ẹrù iṣẹ́
Bóyá o lè dábàá àwọn mélòó kan sí i, ṣùgbọ́n ó dájú pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ń múni ronú. Ojútùú tí Bíbélì pèsè sí àwọn “àṣìṣe tí àìgbọ́n fà” wọ̀nyí ni a kó pọ̀ nínú àwọn àṣẹ méjì pé: “‘Ìwọ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bíi rẹ̀, nìyí, ‘Ìwọ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Lórí àwọn àṣẹ méjì wọ̀nyí ni gbogbo Òfin so kọ́, àti àwọn Wòlíì.”—Mátíù 22:37-40.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]
UPI/Corbis-Bettmann