Ìwé Ìròyìn Kan Tí Ó Níye Lórí
NỌ́Ọ̀SÌ kan kọ àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí sí àwọn òǹṣèwé Jí! láti London:
“Mo ń bá aládùúgbò mi tuntun kan, Jackie, sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ kan nípa iṣẹ́ ìtọ́jú àwọn arúgbó tí mo ń ṣe. Ó wí fún mi pé: ‘Mo ní àwọn ìwé ìròyìn kan tí wọ́n lè fẹ́ láti kà.’ Mo kó àwọn ìwé ìròyìn rẹ̀ náà lọ síbi iṣẹ́, mo sì fi wọ́n sórí àwọn tábìlì tí a ń gbé kọfí sí. Nígbà tí mo tún bẹ ibẹ̀ wò lẹ́yìn náà, mo rí ipa pé ènìyàn ti ṣí àwọn ìwé ìròyìn náà wò dáradára, ó túmọ̀ sí pé àwọn ènìyàn ń kà wọ́n.
“Lẹ́yìn náà, mo wá iṣẹ́ mìíràn, mo sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìwòsàn kan. Mo fi díẹ̀ lára àwọn ìwé ìròyìn aládùúgbò mi náà sí iyàrá ìjókòó-de-dókítà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí i pé àwọn ènìyàn ti kà wọ́n. Lówùúrọ̀ ọjọ́ kan, nígbà tí mo ń tọ́jú ọwọ́ ìyá arúgbó kan, ọkọ rẹ̀ sọ pé: ‘Mo rò pé kò ṣe nǹkan kan pé mo mú ìwé ìròyìn yí ní iyàrá ìjókòó-de-dókítà yín. Ó ní àpilẹ̀kọ kan tí ó dára gan-an tí mo fẹ́ ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú ọmọkùnrin mi.’
“Àwọn ìwé ìròyìn náà ti jẹ́ ìbùkún fún èmi pẹ̀lú. Níwọ̀n bí mo ṣì ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ nọ́ọ̀sì, mo ti lo àwọn ìsọfúnni inú àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí nínú àwọn àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí mi, tí àwọn olùkọ́ mi sì hùwà pa dà lọ́nà rere.
“Aládùúgbò mi, Jackie, jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìwé ìròyìn tí mo sì ti ń sọ nípa rẹ̀ ni Jí! Àwọn ohun tí mo ti kà nínú ìwé ìròyìn yí ti ràn mí lọ́wọ́ láti lóye ohun púpọ̀ nípa ara mi àti nípa ọjọ́ ọ̀la aráyé.”
Bí o bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni nípa bí o ṣe máa gba àwọn ẹ̀dà Jí! tí ń bọ̀ lọ́nà, jọ̀wọ́ kàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ, tàbí kí ó kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.