Ta Lòbí? Ta Lọmọ?
AFÌṢEMỌ̀RÒNÚ kan ní California, U.S.A., dárò nípa bí a ti fi ọlá àṣẹ àwọn òbí wọ́lẹ̀ tó ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Ó kọ̀wé pé: “Ní ọ́fíìsì mi, mo ti gbọ́ àìmọye ìjíròrò láàárín àwọn òbí àti àwọn ọmọ tí wọ́n ń ṣe bí ìgbà tí àwọn àgbàlagbà méjì ń sọ̀rọ̀, tí kì í ṣe bí ọmọ àti òbí. Wọn ti ṣe àdéhùn lórí oríṣiríṣi ọ̀ràn láti orí àkókò àtilọsùn sí owó àfisápò sí àwọn iṣẹ́ ilé lọ́nà tó dà bí ìgbà tí àwọn ilé iṣẹ́ wa títóbi jù lọ bá ń ṣe é. Nígbà míràn, ó ti ṣòro láti mọ ẹni tó jẹ́ òbí yàtọ̀ sí ẹni tó jẹ́ ọmọ.”
Bíbélì pèsè ìmọ̀ràn wíwàdéédéé fún àwọn òbí. Ó kìlọ̀ fún wọn nípa ewu tó wà nínú jíjẹ́ ẹni líle débi pé wọn óò fi máa mú ọmọ wọn bínú, bóyá ní mímú kí ọmọ náà sorí kọ́, kí ó sì rẹ̀wẹ̀sì. (Kólósè 3:21) Ṣùgbọ́n ó tún kìlọ̀ fún àwọn òbí nípa àṣejù lọ́nà kejì—gbígbọ̀jẹ̀gẹ́ jù, yíyẹ ọlá àṣẹ wọn sílẹ̀. Òwe 29:15 sọ pé: “Ọmọ tí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ fún ara rẹ̀, á dójú ti ìyá rẹ̀.” Òwe Bíbélì míràn sọ pé: “Bí ènìyàn bá ń kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àkẹ́jù láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, ní ìkẹyìn ìgbésí ayé rẹ̀, yóò di aláìmọ ọpẹ́ dá pàápàá.” (Òwe 29:21, NW) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa ìránṣẹ́, ìlànà ibẹ̀ kan àwọn ọmọ pẹ̀lú.
Àwọn òbí tí kì í fún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́sọ́nà àti ìbáwí tí wọ́n nílò máa ń jìyà rẹ̀ gidigidi níkẹyìn—ìdílé wọn kì í lákòóso. Ẹ wo bí ó ṣe sàn tó láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò! Lótìítọ́, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń béèrè ìsapá, àmọ́ ó lè mú àwọn àǹfààní wíwàpẹ́títí wá. Bíbélì sọ pé: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó [bá] sì dàgbà tán, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.”—Òwe 22:6.