“Àlàfo Àárín Àwùjọ Àlùfáà àti Àwọn Ọmọ Ìjọ Ń Fẹ̀ Sí I”
ROBERT K. Johnston, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, sọ pé: “Àlàfo àárín àwùjọ àlùfáà àti àwọn ọmọ ìjọ túbọ̀ ń fẹ̀ sí i nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ajíhìnrere ní Amẹ́ríkà.” Nínú ìwé ìròyìn Ministerial Formation, ìwé ìròyìn kan tí Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé ṣe, ó mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn kókó abájọ tí ń fa àìfanimọ́ra yìí: Lójú pákáǹleke tí ń pelemọ sí i nínú ìdílé, àwọn pásítọ̀ ń fẹ́ ìṣètò iṣẹ́ tí ó jọ “ti àwọn dókítà tí ń gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ẹnì kíní kejì lópin ọ̀sẹ̀.” Bí pásítọ̀ bá ṣiṣẹ́ kọjá àkókò, ó ń retí kí wọ́n san àfikún owó fún àṣekún iṣẹ́ náà. Ní àfikún, ọ̀jọ̀gbọ́n náà sọ pé, “bí pákáǹleke ní ti ìwà rere àti ìwà bíbófinmu ti ń pọ̀ sí i,” àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìsìn ń kìlọ̀ fún àwọn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ gboyè jáde lọ́dọ̀ wọn láti dènà ìṣòro nípa mímú “kìkì àwọn ‘ẹlẹgbẹ́’ wọn tí wọ́n jùmọ̀ jẹ́ àlùfáà lọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́,” kí wọ́n sì bá àwọn ọmọ ìjọ lò bí “oníbàárà.” Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ fi wá ń ka àwọn pásítọ̀ wọn mọ́ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀tọ̀kùlú tí kò mọ̀ nípa àwọn àìní àti ìṣòro àwọn gbáàtúù ọmọ ìjọ.
Irú pásítọ̀ wo ni ó lè dín àlàfo náà kù? Ìwádìí kan tí ó ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ìdí tí àwọn pásítọ̀ fí ń kùnà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ṣàwárí pé àwọn ọmọ ìjọ kì í wo ìmọ̀ ìwé àti òye ìmọṣẹ́dunjú tí pásítọ̀ kan ní bí èyí tí ó ṣe kókó. Àwọn mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì kò wá ẹni tí ó ní òye àrà ọ̀tọ̀, tí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ lẹ́nu, tàbí olùṣàkóso jíjáfáfá. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fẹ́ kí pásítọ̀ wọn jẹ́ “ènìyàn Ọlọ́run” tí ń ṣe ohun tí ó ń wàásù rẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Johnston sọ pé, bí kò bá ní ànímọ́ yẹn, “kò sí bí ohun tí ì báà sọ tàbí òye tí ì báà fi hàn ti lè pọ̀ tó” tí yóò dí àlàfo náà.
Àwọn ohun wo ni Bíbélì sọ pé a ń béèrè lọ́wọ́ alàgbà kan nínú ìjọ? “Nítorí náà alábòójútó ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú àṣà ìhùwà, ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú, tí ó wà létòletò, tí ó ní ẹ̀mí aájò àlejò, ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni, kì í ṣe aláriwo ọ̀mùtípara, kì í ṣe aluni, bí kò ṣe afòyebánilò, kì í ṣe aríjàgbá, kì í ṣe olùfẹ́ owó, ọkùnrin kan tí ń ṣe àbójútó agbo ilé ara rẹ̀ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, tí ó ní àwọn ọmọ ní ìtẹríba pẹ̀lú gbogbo ìwà àgbà . . . Ní àfikún, òun tún ní láti ní gbólóhùn ẹ̀rí tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ní òde, kí òun má baà ṣubú sínú ẹ̀gàn àti ìdẹkùn Èṣù.”—Tímótì Kíní 3:2-4, 7.