Aṣọ Chitenge Tó Wúlò Lọ́nà Púpọ̀
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NAMIBIA
AṢỌ chitenge—ṣe o mọ ohun tó jẹ́? Bí o bá lè yọ̀ǹda àkókò díẹ̀, jẹ́ ki á ṣe ìbẹ̀wò ráńpẹ́ sí abúlé kan nílẹ̀ Áfíríkà, kí a sì rí aṣọ chitenge tó wúlò lọ́nà púpọ̀ níbi iṣẹ́ àti níbi eré.
Abúlé tí a ń ṣèbẹ̀wò sí náà ni Rundu, Namibia. Ibi àkọ́kọ́ tí a dúró ni ọjà kan tí títà àti rírà ti ń lọ ní pẹrẹwu. Àwọn obìnrin tí ojú wọn ń dán ń dúnàádúrà, wọ́n ń rajà, wọ́n ń tajà, tàbí wọ́n wulẹ̀ dúró ń tàkurọ̀sọ. Àmọ́, fara balẹ̀ wò wọ́n díẹ̀ sí i, o lè kíyè sí i pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo wọn ló wọ oríṣi aṣọ kan tó hàn yàtọ̀, ìró kan tí a mọ̀ sí chitenge.
Aṣọ chitenge olówùú náà gùn ní mítà méjì, ó fẹ̀ ní mítà kan àtàabọ̀, ó sì ní onírúurú àìlóǹkà àwọ̀ àti àwòrán. Àwọn kan ní àwòrán ẹranko, àwọn mìíràn sì ní àwòrán ènìyàn tàbí ti ìrísí ojú ilẹ̀.
Lẹ́yìn náà, a bẹ àwọn ará abúlé náà mélòó kan wò nínú àwọn ilé wọn tí wọ́n fi amọ̀ mọ, tí wọ́n sì fí imọ̀ bò dáradára. Ọwọ́ àwọn obìnrin náà dí lẹ́nu iṣẹ́ ilé wọn—gbígbá ilẹ̀ iwájú ilé wọn tàbí dídáná oúnjẹ tí ìdílé náà máa jẹ. Àwọn kan wọ aṣọ chitenge kan nìkan, lọ́tẹ̀ yí, wọ́n fà á sókè, wọ́n sì ró o mọ́ àyà bí aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ kan. Nígbà tí àwọn obìnrin náà bá wọ aṣọ—bóyá tí wọ́n wọ ẹ̀wù àwọ̀débàdí kan àti síkẹ́ẹ̀tì kan—wọn yóò ró aṣọ chitenge kan sí ìbàdí lé orí síkẹ́ẹ̀tì náà kí ó má bàa dọ̀tí nígbà tí wọ́n bá ń rìn lọ lójúu títì eléruku abúlé náà.
Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ arẹwà obìnrin yẹn? Ó fi odindi aṣọ chitenge—tó fẹ̀ ní mítà méjì—wé gèlè dáradára kan. Wo bí ó ṣe pọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú. Aṣọ chitenge míràn ló so, tó fi gbé ọmọ rẹ̀ kọ́ èjìká kan. Inú ọmọ rẹ̀ ń dùn gan-an pé Màmá òun pọn òun báyìí. Bí ọmọ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í ké, ìyá rẹ̀ yóò kàn fa aṣọ tó so náà níwájú, yóò sì máa fún ọmọ náà lọ́mú mu, tàbí kí ó máa rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, bí ó ṣe ń rìn lọ.
O tún lè ti kíyè sí i pé ó ta owó rẹ̀ ní kókó sétí aṣọ tó ró—àsùnwọ̀n kan tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún un. Lẹ́yìn tó bá ti ra àwọn ohun tó fẹ́ rà, yóò tú aṣọ chitenge míràn, yóò kó àwọn ẹ̀fọ́ náà sí i, yóò fi dì wọ́n dáradára, yóò sì gbé àpò ìkẹ́rù oúnjẹ náà rù lọ́ sílé.
Nígbà tí ó bá wọ ilé rẹ̀, ìwọ yóò rí àwọn ọ̀nà míràn tí a ń gbà lo aṣọ tó wúlò lọ́nà púpọ̀ yí. Níwájú ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan ni a gbé aṣọ chitenge aláwọ̀ mèremère kọ́. Bí o ti lè rí i, kò sí àwọn ògiri ìkélé. Okùn gígùn kan ni a ń so láti ìkángun kan ibùgbé náà dé èkejì, tí a ń fi aṣọ chitenge mẹ́rin kọ́, tí a fi ń ya ibi ìnàjú inú ilé kúrò lára ibùsùn.
Obìnrin tó gbà wá lálejò sọ ẹ̀fọ́ rẹ̀ kalẹ̀, ó sì rí i pé òun ko ní igi ìdáná. Kí ó tó wọ igbó lọ ṣẹ́ ẹrù igi kan, ó rí i dájú pé òun mú àfikún aṣọ chitenge kan dání. Lẹ́yìn tí ó ṣẹ́gi náà tán, ó fi aṣọ chitenge kan di igi náà pọ̀. Ó wá mú aṣọ chitenge míràn, ó sì fi ṣu òṣùká. Òṣùká yìí ló fi ru ẹrù igi náà lọ sílé.
Lẹ́yìn tí oúnjẹ ọ̀rẹ́ wa fẹ bẹ̀rẹ̀ sí í hó, ó pinnu pé òun ní àkókò láti ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ aládùúgbò òun. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, tó sì ń fara ṣàpèjúwe, ó tẹ́ aṣọ chitenge rẹ̀ sílẹ̀ bíi kúbùsù, ó sì tẹ́ ọmọ rẹ̀ lé e. Ọmọ náà fìdùnnú hàn sí ìyá rẹ̀ tó fún un ní igi kékeré kan láti máa fi ṣeré nípa rírẹ́rìn-ín músẹ́.
Láìpẹ́, ọ̀rẹ́ wa ní láti pa dà lọ yẹ oúnjẹ tó ń sè wò. Ṣùgbọ́n òjò ti ṣú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ lójijì. Láìdààmú rárá, ó gbé ọmọ rẹ̀ kọ́ apá kan, ó sì fi aṣọ chitenge náà bo orí rẹ̀. Pẹ̀lú agbòjò àtọwọ́dá rẹ̀ tí wọ́n fi borí, ó forí lé ọ̀nà ilé láti bójú tó oúnjẹ náà.
Síkẹ́ẹ̀tì, àwọ̀kanlẹ̀, àsùnwọ̀n, àpò ìkẹ́rù oúnjẹ, òṣùká, kúbùsù, agbòjò, ìpọnmọ, gèlè—ó jọ pé ohun tí a ń lo aṣọ chitenge fún kò lóǹkà, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀rí bí àwọn ará Áfíríkà wọ̀nyí ṣe lè hùmọ̀ nǹkan.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Aṣọ “chitenge” wúlò lọ́nà púpọ̀: bí okùn ìdigi, ìgbọ́mọkọ́, gèlè dáradára, kúbùsù rírẹwà