Ó Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Má Jà Mọ́
Ọmọdékùnrin ọlọ́dún 11 kan láti California, U.S.A., kọ̀wé sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York, pé:
“Mo nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé yín, ní pàtàkì Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Kí a tó gba ìwé náà, èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin máa ń jà ṣáá ni. Lọ́jọ́ kan, a pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yẹn, a sì wá rí i pé a kò ṣe ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí a ṣe.
“Ìwé yìí ràn wá lọ́wọ́ gan-an. Mo mọrírì rẹ̀, mo sì rọ àwọn ìdílé mìíràn láti ka ìwé yìí nítorí ó fakọ yọ. Ó tún ń ran ìdílé mi lọ́wọ́ láti rí àlàáfíà àti ayọ̀ nínú ilé wa.”
Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé jẹ́ ìwé olójú ewé 192 tí ó jíròrò àwọn kókó ẹ̀kọ́ wíwúlò bíi “Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Agbára Ìdarí Apanirun,” “Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Nínú Agbo Ilé Rẹ,” àti “Ìwọ́ Lè Borí Àwọn Ìṣòro Tí Ń Ṣe Ìdílé Lọ́ṣẹ́.”
Fún ìsọfúnni nípa bí ó ṣe lè rí ẹnì kan tí yóò máa wá bá ọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé rẹ̀, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.