Jí!—“Ohun Èlò Pàtàkì Tí Kò Ṣeé Máà Ní”
“Ẹ ṢEUN fún àpilẹ̀kọ yín tí ó ní àkọlé ‘Àrùn RSD—Àrùn Ríronilára Kan Tí Ń Rúni Lójú,’ nínú ìtẹ̀jáde ti September 8, 1997. Gẹ́gẹ́ bí akọ̀ròyìn ilé ẹjọ́, wọ́n sábà máa ń pè mí pé kí n wá ṣàkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀rí onírúurú ọ̀ràn dídíjú. Láìpẹ́ yìí, mo kọ ìròyìn ọ̀rọ̀ tí oníṣègùn apàmọ̀lára kan, tí ó fi àbójútó ìlera ṣe lájorí iṣẹ́ rẹ̀, sọ. Gbogbo ọ̀ràn náà dá lé orí àrùn RSD [Àrùn Ìṣiṣẹ́gbòdì Iṣan Amúnimọ̀rora]. Nítorí pé mo máa ń ka Jí! déédéé, kíákíá ni mo ti mọ àwọn èdè ọ̀rọ̀ tí a ń lò àti àwọn oríṣiríṣi ọ̀nà ìṣètọ́jú, tí ẹ ti ṣàlàyé gbogbo wọn ní kedere nínú ìtẹ̀jáde September náà. Lẹ́yìn náà, mo bá àwọn agbẹjọ́rò tí ọ̀ràn náà kàn ṣàjọpín àpilẹ̀kọ yìí.
“Mo ka Jí! sí ohun èlò pàtàkì tí kò ṣeé máà ní nínú ẹ̀kọ́ tí mo ń kọ́ lọ́wọ́. Ó ń fún mi ní ìsọfúnni kíkún nípa ẹgbàágbèje kókó ẹ̀kọ́.—G. M. A.”
Bi o bá fẹ́ gba ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́, tí a ń tẹ̀ jáde ní èdè 81 nísinsìnyí, gbà, jọ̀wọ́ kàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò rẹ, tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó sún mọ́ ọ jù lọ nínú àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.