ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 8/8 ojú ìwé 32
  • “Nǹkan Àrà Ọ̀tọ̀ Kan”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Nǹkan Àrà Ọ̀tọ̀ Kan”
  • Jí!—1998
Jí!—1998
g98 8/8 ojú ìwé 32

“Nǹkan Àrà Ọ̀tọ̀ Kan”

Lẹ́yìn tí obìnrin ọmọ 70 ọdún kan, ní Moscow, Rọ́ṣíà, ka ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, ìwé tó gbé gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbésí ayé Jésù tí a kọ sínú àwọn Ìwé Ìhìnrere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jáde, ó wí pé: “N kò ka irú ìwé bẹ́ẹ̀ rí. Mo fẹ́ mọ̀ sí i nípa Ọlọ́run àti Jésù Kristi, mo sì tilẹ̀ fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pàápàá.”

Lọ́pọ̀ ìgbà ni ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà máa ń gba irú lẹ́tà bẹ́ẹ̀ nípa àwọn ìwé tí ń ṣàlàyé Bíbélì. Obìnrin kan ní Chelyabinsk, ìlú tó ní èrò tó lé ní mílíọ̀nù kan nínú, tó wà ní nǹkan bí 1,500 kìlómítà ní ìhà ìlà oòrùn Gúúsù Moscow, tún kọ irú rẹ̀ kan ránṣẹ́.

Ó sọ nípa ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí pé: “Ìwé náà jẹ́ nǹkan àrà ọ̀tọ̀ kan. Ó ń gbin ìrètí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ sọ́kàn àwọn ènìyàn, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa ìtàn àtijọ́. Kí n tó ka ìwé yìí, n kò ronú nípa Ọlọ́run rí, bẹ́ẹ̀ ni ìsìn kò jẹ mí lọ́kàn, ṣùgbọ́n ní báyìí, mo fẹ́ ṣe batisí. Mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé yín. Mo fẹ́ máa bá àwọn ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀, àti ìbátan mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí mo ti kà.”

Ìwọ pẹ̀lú lè gba àwọn ìwé tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa Jésù àti ìrètí ìwàláàyè nínú ayé tuntun kan, tí a gbé karí Bíbélì. Bí o bá ń fẹ́ ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà kan ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí gbà, tàbí tí o ń fẹ́ kí ẹnì kan kàn sí ọ nílé rẹ láti bá ọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tó ṣe wẹ́kú nínú èyí tí a tò sí ojú ìwé 5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́