“Ayé Kan Tí Àlàáfíà àti Ìṣọ̀kan Yóò Wà”
Ǹjẹ́ o gbà gbọ́ pé èyí lè ṣeé ṣe láé? Obìnrin kan láti Florida, U.S.A., kọ̀wé pé: “Ìwé àṣàrò kúkúrú yín náà, Gbogbo Ènìyàn Yóò Ha Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn Láé Bí?, jẹ́ ọ̀kan lára ìsọfúnni tí ń fúnni nírètí tí ó lágbára gan-an tí mo tí ì kà rí. Mo ti kà á lọ́pọ̀ ìgbà. Gbogbo ìgbà tí mo bá kà á ni inú mi máa ń dùn—tí mo bá ronú nípa ayé kan tí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan yóò wà.”
Bí o bá fẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ènìyàn lè gbé ayé kan lálàáfíà àti níṣọ̀kan, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5. A óò fi ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 náà, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, ránṣẹ́ sí ọ. A lérò pé apá 10, “Ayé Titun Iyanu naa ti Ọlọrun Ṣe,” yóò mú inú rẹ dùn.