ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 11/8 ojú ìwé 32
  • “Jí! Ló Ní Ìsọfúnni Tó Dára Jù”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Jí! Ló Ní Ìsọfúnni Tó Dára Jù”
  • Jí!—1998
Jí!—1998
g98 11/8 ojú ìwé 32

“Jí! Ló Ní Ìsọfúnni Tó Dára Jù”

Ohun tí ọmọkùnrin Mùsùlùmí ọlọ́dún 16 kan sọ ní Ìlú Benin, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó wà ní ilẹ̀ Áfíríkà la kọ sókè yìí. Nínú lẹ́tà kan tó kọ sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà, ó wí pé:

“Mo rí Jí! nílé ọ̀rẹ́ mi kan, mo sì yá ìtẹ̀jáde mẹ́sàn-án. Mo ka gbogbo wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí lọ́jọ́ kan ṣoṣo! Mo ń kọ̀wé láti yin gbogbo àwọn tó ṣiṣẹ́ láti mú kí Jí! máa jáde—títí kan Jèhófà—fún iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń ṣe! Ohun tó wọ̀ mí lọ́kàn jù ni bí ẹ ṣe ń so àwọn ọ̀ràn tó tan mọ́ àyíká pọ̀ mọ́ Bíbélì àti Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ẹgbẹ́ Ààbò Ẹ̀dá ní Nàìjíríà, mo ti ń wá àwọn ìwé tí n óò kó sí ibi ìkówèésí tèmi fúnra mi nípa àyíká àti ìṣẹ̀dá. Mo wá mọ̀ nísinsìnyí pé Jí! ló ní ìsọfúnni tó dára jù. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè máa rí ìtẹ̀jáde Jí! méjèèjì tí ń jáde lóṣù (lédè Gẹ̀ẹ́sì) gbà tààràtà láti ọ̀dọ̀ yín.”

Bóyá o kò ka Jí! rí kí o tó rí eléyìí. Bí o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.

□ Mo fẹ́ mọ bí mo ṣe lè rí ẹ̀dà Jí kan gbà.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Ayé: Nípasẹ̀ Ìyọ̀ǹda Onínúure Replogle Globes, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́