Àpilẹ̀ṣe Ha Nílò Olùpilẹ̀ṣẹ̀ kan Bí?
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń ronú lórí ìbéèrè yẹn lónìí. Kí ni èrò tìrẹ? Ọkùnrin kan láti Virginia, U.S.A., kọ̀wé pé:
“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? tán ni. Mo rí i pé ìwádìí tí wọ́n ṣe lórí rẹ̀ ṣe kínníkínní, ó sì ń múni ronú jinlẹ̀. Ọdún mélòó kan sẹ́yìn ni mo gba ìwé náà lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn míṣọ́nnárì yín ní Summerville, South Carolina, U.S.A.
“Mo mọrírì ìwé náà àti bí ó ṣe sọ̀rọ̀ gbe ìṣẹ̀dá lọ́nà ti ìlànà sáyẹ́ǹsì. Iwé yín náà kò jẹ́ kí n tún ronú mọ́ pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ Ìjọ Kátólíìkì ti Róòmù ni mí látilẹ̀wá, mo gbádùn ìwé yìí àti àwọn ìjíròrò mi pẹ̀lú díẹ̀ lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ẹlẹgbẹ́ yín tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì.”
Bí ìwọ pẹ̀lú bá fẹ́ rí ìdánilójú tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé pé ìwàláàyè kò ṣèèṣì wà ṣùgbọ́n pé a ṣẹ̀dá rẹ̀ ni, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5. Inú wa yóò dùn láti fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí ọ nípa bí o ṣe lè rí ìwé pẹlẹbẹ olójú-ìwé 32 náà, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, gbà. Kọ́ nípa àgbàyanu ọ̀nà àpilẹ̀ṣe tí ó wà lára àwọn ohun alààyè àti ìdí tí irú àpilẹ̀ṣe bẹ́ẹ̀ fi wá láti ọwọ́ Olùpilẹ̀ṣe kan.
□ Ẹ fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí mi nípa bí mo ṣe lè rí ìwé pẹlẹbẹ náà, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, gbà.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Gbogbo àwòrán jẹ́ ti: The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck