Ó Rí Ìrànwọ́ Gbà Nínú Ìwákiri Rẹ̀
NǸKAN kò rọgbọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn jákèjádò ayé, àwọn kan sì ń wá ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ káàkiri. Ọkùnrin ọlọ́dún márùndílógójì kan tí ó ní àwọn ọmọ méjì kọ̀wé láti ìlú ńlá Grodno, Belarus pé:
“Obìnrin kan dá mi dúró ní òpópó ọ̀nà, ó sì fi ìwé ìròyìn Jí! lọ̀ mí. N kò mọ ohun tó wà nínú ìwé ìròyìn náà, àmọ́, mo gbà á, nítorí pé ó fani mọ́ra. Nígbà tí mo délé, mo yẹ àwọn àpilẹ̀kọ inú rẹ̀ wò, wọ́n sì gba àfiyèsí mi.
“N kò ronú pé mo jẹ́ onígbàgbọ́. Àmọ́, ìtẹ̀jáde yín fún mi ní àwọn ìdáhùn tó múná dóko sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ń dà mí láàmú. Ìgbésí ayé wa kò rọrùn báyìí, àti pé àwa pàápàá nílò ìrànlọ́wọ́ Bíbélì. Mo fẹ́ bẹ̀ yín kí ẹ túbọ̀ fi ìsọfúnni nípa Ọlọ́run àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ránṣẹ́ sí mi. Ó ti pẹ́ tí mo ti ń wá ìdáhùn sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè, ìtẹ̀jáde yín sì ti ràn mí lọ́wọ́ nínú ìwákiri mi.”
Ìtẹ̀jáde ṣíṣeyebíye tí ó ti ran ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn lọ́wọ́ ni ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n náà, Ki Ni Ète Igbesi-Aye?—Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I? O lè rí ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà kan gbà nípa kíkọ̀wé kún fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tí a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ wẹ́kú lára àwọn tí a tó sí ojú ìwé karùn-ún ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ sọ fún mi bí mo ṣe lè rí ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ Ki Ni Ète Igbesi-Aye?—Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I? gbà.
Kọ èdè tí o fẹ́․
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.