Ó Lè Mú Kí Ìdílé Rẹ Tòrò Sí I
ÌYÁ kan tó bímọ mẹ́rin tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ọdún méjìlá sí ọdún méjìlélógún sọ pé: “Mo mọ̀ pé àá rí ọ̀pọ̀ ìdílé tí á fẹ́ lo ìwé yìí láti tún ipò nǹkan ṣe nínú ilé wọn.” Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé ló ń tọ́ka sí yẹn.
Ìyá tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta yẹn, tó wá láti New Zealand, sọ nípa ìwé náà pé: “Wọ́n lo ìrònújinlẹ̀ àti òye tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn ìdílé nígbà tí wọ́n ń kọ ìwé náà.”
Ìwé Ayọ̀ Ìdílé lè ṣe gbogbo mẹ́ńbà ìdílé láǹfààní—àwọn ọkọ, àwọn ìyàwó, àwọn òbí, àwọn ọmọ, àwọn òbí àgbà—bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ilé. Lára àwọn àkòrí tí ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ ni “Mímúra Sílẹ̀ fún Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí,” “Báwo Ni O Ṣe Lè Bójú Tó Agbo Ilé?,” “Ìwọ́ Lè Borí Àwọn Ìṣòro Tí Ń Ṣe Ìdílé Lọ́ṣẹ́,” àti “Dídàgbà Pọ̀.”
Láti rí ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà tìrẹ gbà, jọ̀wọ́ kọ̀wé kún fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́. Wàá rí àwọn àbá pàtó tí o lè lò láti yanjú àwọn ìṣòro, tí yóò sì mú kí ìgbésí ayé ìdílé gbádùn mọ́ni bí Ẹlẹ́dàá ṣe fẹ́ kó rí.
□ Ẹ fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí mi nípa bí mo ṣe lè rí ìwé náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, gbà.
Sọ èdè tí o fẹ́.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.