Inú Jí! Ló Ti Rí Àwòrán Tó Lò fún Ìwé Ìpolongo Ìlòdìsí Sìgá Mímu
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍTÁLÌ
LÁÌPẸ́ yìí, nílùú Mortara ní àríwá Ítálì, Ìgbìmọ̀ Tí Ń Gbógun Ti Àrùn Jẹjẹrẹ ní Ítálì àti ìwé ìròyìn kan ládùúgbò yẹn, ṣètò ìdíje kan láàárín àwọn ọmọléèwé girama láti yàwòrán ìwé ìsọfúnni tí a máa ń lẹ̀ sígboro láti fi polongo ìlòdìsí sìgá mímu. Simona ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, tó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lọ yẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtẹ̀jáde Jí! wò, láti lè rí ìsọfúnni nípa àwọn ewu tí ń bá tábà mímu rìn, pàápàá jù lọ ìtẹ̀jáde January 8, 1990, àti ti May 22, 1995. Simona kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo ń ṣe ìwádìí náà, àwòrán tó wà níwájú ìtẹ̀jáde wọ̀nyí gba àfiyèsí mi. Mo yàwòrán agbárí táa fi sìgá há lẹ́nu, irú èyí tí mo rí nínú Jí!, àkòrí iwájú ìwé ìròyìn náà ló sì jẹ́ kí n mọ ọ̀rọ̀ amóríwú tí mo lò.” Ọ̀rọ̀ amóríwú tó lò ni, “Sìgá Mímu—Ó Ń Pa Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Èèyàn Láti Lè Pa Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Owó Wọlé.” Ìwé ìpolongo rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àádọ́ta-lé-rúgba tó wọnú ìdíje náà.
Bí Simona tilẹ̀ kéré lọ́jọ́ orí sí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọléèwé yòókù tí wọ́n jọ ń díje, òun ló gba ẹ̀bùn kìíní, tó tún ní nínú ọ̀ọ́dúnrún owó dọ́là tí í ṣe ẹ̀bùn ìrànwọ́ ẹ̀kọ́. Simona kọ̀wé sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society láti fọpẹ́ hàn fún àwọn ìsọfúnni gbígbámúṣé tó máa ń wà níwájú ìwé ìròyìn Jí! tó kọ́ ọ lóhun tó lò. Kì í ṣe iwájú Jí! nìkan ló máa ń gbádùn kíkà rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún ń gbádùn àwọn àpilẹ̀kọ inú rẹ̀ tó bá àkókò mu tó sì gbéṣẹ́, àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí ọ̀ràn ìlera, àwọn ohun tí ń lọ lọ́wọ́, àti àwọn ìṣòro táwọn ọ̀dọ́ ń dojú kọ. Ó parí lẹ́tà rẹ̀ báyìí: “ÀFIKÚN ÀLÀYÉ: Ẹ máa bá iṣẹ́ rere tí ẹ ń ṣe lọ!”
Bí o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ọ̀ràn mìíràn tó kan àwọn Kristẹni, jọ̀wọ́ lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kí o gé fọ́ọ̀mù ìsàlẹ̀ yìí ránṣẹ́.
□ Ẹ fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí mi nípa bí mo ṣe lè rí ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, gbà.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.