ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 3/8 ojú ìwé 32
  • “Ó Yẹ Kí N Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọ́run”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ó Yẹ Kí N Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọ́run”
  • Jí!—2000
Jí!—2000
g00 3/8 ojú ìwé 32

“Ó Yẹ Kí N Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọ́run”

Ẹnì kan ló ju lẹ́tà tó wà nísàlẹ̀ yìí sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Edmonton, Alberta, Kánádà.

“Ońṣẹ́ Ọ̀wọ́n:

“Mo kọ ìwé yìí láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó mú kí iṣẹ́ ìyanu kan ṣẹlẹ̀ nínú ayé mi, ẹni náà sì lè ṣàìmọ̀ o.

“Lọ́sẹ̀ bíi mélòó kan sẹ́yìn, èmi àti ọkọ mi ń jiyàn kíkankíkan nípa nǹkan kan. Bí mo ṣe sọ pé, ‘Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe kékeré o, mi ò sì rò pé ó lè tán lọ́kàn mi.’ Bẹ́ẹ̀ ni ẹnì kan kanlẹ̀kùn. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń kanlẹ̀kùn mi yìí, mi ò sì lè sá pamọ́ fún un mọ́.

“Nígbà tí mo ṣílẹ̀kùn, ọkàn mi ò tiẹ̀ sí nínú ohun tó ń sọ rárá. Àwọn ọ̀rọ̀ tí mo kàn rántí ni ‘àwọn ọmọ’ àti ‘ìdílé.’ Ọkùnrin náà yọ ìwé kan jáde tó ń jẹ́ Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Nígbà tí mo rí àkọlé rẹ̀, ńṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí sunkún, mi ò sì yé ẹkún sun. Ó wòkè, ó sì bẹ̀ mí pé kí n máà bínú pé òun dí mi lọ́wọ́, ó mú ìwé náà fún mi, ó sì jáde.

“Kí wá ni iṣẹ́ ìyanu náà? Ìránnilétí náà pé kí n má ṣèyọnu tí mi ò bá mọ ohun tí mo lè ṣe, nítorí pé Ọlọ́run mọ̀ ọ́n. Ó yẹ kí n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Kódà, ó rán ẹnì kan sí mi. Ẹ ṣeun o.”

Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé lè ran olúkúlùkù mẹ́ńbà ìdílé lọ́wọ́. Díẹ̀ lára àwọn àkórí táa lè rẹ́kọ̀ọ́ kọ́ nínú ẹ̀ ni “Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Agbára Ìdarí Apanirun,” “Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Nínú Agbo Ilé Rẹ,” àti “Ìwọ́ Lè Borí Àwọn Ìṣòro Ti Ń Ṣe Ìdílé Lọ́ṣẹ́.”

Bóo bá fẹ́ ẹ̀dà kan rẹ̀, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ sára rẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí. A ó ṣàlàyé pàtó fún ẹ, èyí tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro, tí ìwọ yóò sì máa gbádùn ìdílé rẹ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá ṣe fẹ́ kó rí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́