April 19, 2000 Ọjọ́ Tó Yẹ Ká Máa Rántí
LÁLẸ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú, ó fi ìṣe ìrántí ikú rẹ̀ lélẹ̀. Ayẹyẹ tí ò fa ariwo ni. Nígbà ayẹyẹ náà, ó wí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.
Lọ́dún yìí, àyájọ́ ayẹyẹ náà bọ́ sí ọjọ́ Wednesday April 19, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀.
Nítorí èyí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé yóò pàdé pọ̀ lálẹ́ ọjọ́ pàtàkì yìí láti ṣe Ìṣe Ìrántí náà bí Jésù ṣe ní ká máa ṣe é. A fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ké sí ọ láti wá bá wa ṣe ayẹyẹ yìí. Jọ̀ọ́, wádìí àkókò àti ibi tí wọ́n ti máa ṣe ìpàdé náà lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ.