Rírí Ohun Tó Sọnù He
Lọ́dún tó kọjá, ní ìpínlẹ̀ Maryland, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ọkùnrin kan rọra fi ohùn pẹ̀lẹ́ kọ àwọn ìwé ìròyìn llé Iṣọ́ àti Jí! tí wọ́n fi lọ̀ ọ́. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré bi í pé ṣé kí òun gba àwọn ìwé náà, bàbá rẹ̀ sì sọ pé ó lè gbà wọ́n. Àwọn méjèèjì jọ tún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn ṣe, wọ́n sì lọ da ìdọ̀tí nù sínú ike ìdàdọ̀tísí kan ní tòsí. Ẹlẹ́rìí tó fún wọn níwèé náà ń ṣàníyàn pé wọ́n mà lè lọ da àwọn ìwé ìròyìn náà nù. Ló bá pinnu láti padà lọ síbi ike ìdàdọ̀tísí náà láti lọ yẹ ibẹ̀ wò.
Kò rí àwọn ìwé ìròyìn náà níbẹ̀, ṣùgbọ́n ó rí àpò ìfàlọ́wọ́ kan àti àpamọ́wọ́ kan níbẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì náà wá obìnrin tí àdírẹ́sì rẹ̀ wà nínú àpò náà lọ. Nígbà tí wọ́n ń sún mọ́ tòsí ilé obìnrin náà, wọ́n rí obìnrin kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ wà láàárín ogójì sí ọgọ́ta ọdún tó ń mú akọ ẹṣin kan lọ sí ilé ẹran. Nígbà tí wọ́n kó àwọn ohun tí wọ́n rí náà fún obìnrin náà, ó kígbe pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, àwọn ìwé tó ṣe pàtàkì ló wà nínú rẹ̀—àwọn bíi ìwé àṣẹ ìrìnnà mi, ìwé sọ̀wédowó mi, káàdì ìrajà àwìn mi, àti àwọn ìwé nípa ẹṣin mi.” Ó ní alẹ́ àná ni wọ́n jí àwọn àpò náà lọ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé díẹ̀ ló kù kí wọ́n lọ da ìdọ̀tí tó wà nínú ike ìdàdọ̀tísí náà nù, Ọlọ́run ló ṣe é tí wọ́n lọ yẹ inú rẹ̀ wò.
Obìnrin náà fún wọn ní nǹkan, ṣùgbọ́n dípò kí tọkọtaya náà gbà á, ńṣe ni wọ́n fún obìnrin náà ní ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? nígbà tí wọ́n gbé àpò àti àpamọ́wọ́ náà fún un. Láti fi ìmoore hàn, obìnrin náà kọ ìwé sọ̀wédowó fún wọn láti fi ṣètìlẹ́yìn fún ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ pípín irú àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì bẹ́ẹ̀ kárí ayé. Láti ìgbà yẹn, obìnrin náà ti ń fìfẹ́ hàn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Bóo bá fẹ́ ẹ̀dà kan ìwé olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ sínú fọ́ọ̀mù náà, tàbí kí o fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí táa tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
◻ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi láti bá mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.