Ǹjẹ́ o Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 23. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Nígbà tí kò sẹ́ni tó fẹnu ara rẹ̀ jẹ́wọ́, báwo ni àṣírí ẹni tó ṣẹ̀ ṣe wá tú nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Áì nítorí pé wọn kò ṣègbọràn sí ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún wọn nípa Jẹ́ríkò? (Jóṣúà 7:14-21)
2. Èé ṣe tí Jèhófà fi pa Ónánì tí í ṣe ọmọ Júdà? (Jẹ́nẹ́sísì 38:7-10)
3. Ta ni ẹni tó rò pé obìnrin olódodo náà, Hánà, mutí yó ni, tó sì bá a wí? (1 Sámúẹ́lì 1:13, 14)
4. Èé ṣe tí Jésù fi sọ pé àwọn akọ̀wé òfin yóò “gba ìdájọ́ tí ó wúwo jù”? (Lúùkù 20:46, 47)
5. Ta ló kọ ìwé Kíróníkà méjèèjì? (Nehemáyà 12:26)
6. Kí ni a lò lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nínú Bíbélì láti fi ṣàpèjúwe àǹfààní agbára lílò? (Jeremáyà 32:17)
7. Ọ̀rọ̀ wo ni Bíbélì lò fún ìwọ̀n fífẹ̀ ilẹ̀ tí àwọn akọ màlúù tí a so pọ̀ lè tú lóòjọ́? (1 Sámúẹ́lì 14:14)
8. Ìhà ibo ni Négébù wà ní ilẹ̀ Palẹ́sìnì? (Ẹ́kísódù 26:18)
9. Àtọmọdọ́mọ èwo lára àwọn ọmọkùnrin Nóà ni àwọn ará Íjíbítì, àwọn ará Etiópíà, àti àwọn ọmọ Kénáánì jẹ́? (Jẹ́nẹ́sísì 10:6)
10. Inú oṣù àfòṣùpákà wo ni wọ́n parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì? (1 Àwọn Ọba 6:38)
11. Igi wo ló kó ipa pàtàkì nínú ṣíṣẹ́gun tí Dáfídì ṣẹ́gun àwọn Filísínì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Réfáímù? (2 Sámúẹ́lì 5:24)
12. Ọ̀nà wo, tó jẹ́ àfikún, ni ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kẹrin nínú Ìṣípayá gbà pa àwọn tó pa? (Ìṣípayá 6:8)
13. Èé ṣe tí wọ́n fi ń pe àwọn Néfílímù ní “àwọn ọkùnrin olókìkí”? (Jẹ́nẹ́sísì 6:4)
14. Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pa á láṣẹ, kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kí àwọn ìran ọjọ́ iwájú lè rí mánà tí wọ́n jẹ nínú aginjù? (Ẹ́kísódù 16:32, 33)
15. Kí ni Tímótì mọ̀ “láti ìgbà ọmọdé jòjòló” tí yóò sọ ọ́ di “ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà”? (2 Tímótì 3:15)
16. Ta ló gbé òkú Sọ́ọ̀lù àti ti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kúrò lára ògiri Bẹti-ṣánì tí àwọn Filísínì gbé wọn kọ́ sí, tí wọ́n sì lọ sin wọ́n lọ́nà tó níyì? (1 Sámúẹ́lì 31:11-13)
17. Ibo ni Jésù ti ké sí Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù láti wá di ọmọ ẹ̀yìn òun? (Mátíù 4:18-22)
18. Ọba Ásíríà wo ni Ménáhémù, tí í ṣe ọba Ísírẹ́lì, fún ní ìṣákọ́lẹ̀ kí ó lè fi Ísírẹ́lì lọ́rùn sílẹ̀? (2 Àwọn Ọba 15:19)
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Jèhófà dán orílẹ̀-èdè náà wò, ó kọ́kọ́ ya ẹ̀yà náà sọ́tọ̀, lẹ́yìn náà ìdílé, lẹ́yìn náà agbo ilé, àti níkẹyìn ọkùnrin náà, Ákáánì
2. Nítorí pé ó ṣàìgbọràn sí bàbá rẹ̀, ó sì ṣe ojúkòkòrò, Ónánì kò fẹ́ mú irú ọmọ jáde fún arákùnrin rẹ̀, Éérì, tó kú
3. Àlùfáà àgbà Élì
4. Nítorí pé wọ́n ń fẹ́ jẹ́ ẹni tó yọrí ọlá ní dandan, wọ́n ń fi ìwọra “jẹ ilé àwọn opó run,” wọ́n sì ń fi gbígba àdúrà gígùn ṣe bojúbojú bí ẹni tó jẹ́ mímọ́
5. Ẹ́sírà
6. Apá
7. Sarè
8. Ìhà gúúsù
9. Hámù
10. Búlì
11. Bákà
12. Nípa “ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani”
13. Kì í ṣe òkìkí tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run ni èyí tọ́ka sí bí kò ṣe ìfòyà tí wọ́n tàn kálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí abúmọ́ni àti òṣìkà agbonimọ́lẹ̀
14. Wọ́n da mánà ẹ̀kún òṣùwọ̀n ómérì sínú ìṣà kan, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ “níwájú Jèhófà”
15. “Ìwé Mímọ́”
16. Àwọn akíkanjú ọkùnrin láti Jabẹṣi-gílíádì
17. Òkun Gálílì
18. Púlì (Tigilati-pílésà Kẹta)