À Ń ké Sí Ọ—Ṣé Wàá Wá?
IBO LA NÍ KÓ O WÁ? Ibi ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù lọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe lọ́dọọdún ni, ìyẹn àjọ̀dún ikú Kristi tí a gbé karí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tó dá sílẹ̀. Àkọsílẹ̀ Mátíù sọ fún wa pé: “Jésù mú ìṣù búrẹ́dì kan, lẹ́yìn sísúre, ó bù ú, ní fífi í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí pé: ‘Ẹ gbà, ẹ jẹ. Èyí túmọ̀ sí ara mi.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó mú ife kan àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín; nítorí èyí túmọ̀ sí “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.’”—Mátíù 26:26-28.
A ó ṣàlàyé lórí bí àwọn ọ̀rọ̀ yìí ti ṣe pàtàkì tó níbi ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ti ọdún yìí, tí ó bọ́ sí ọjọ́ Thursday, March 28, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. À ń retí rẹ. Jọ̀wọ́ béèrè àkókò ìpàdé náà àti ibi tá a ti máa ṣe é lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò rẹ. A ó gbà ọ́ tọwọ́tẹsẹ̀.