‘Ṣókí Lọ̀rọ̀ Inú Ẹ̀, Ṣùgbọ́n ó Kún Fún Ẹ̀kọ́’
Bí obìnrin kan ṣe ṣàpèjúwe ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? nìyẹn. Lẹ́yìn náà ló wá ṣàlàyé ohun tó sún un tó fi ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà yẹn. Ó sọ pé: “Nípa lílo ìwé pẹlẹbẹ yìí, obìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Gloria ti sọ ìfẹ́ tó ní fún kíka Bíbélì dọ̀tun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lè jókòó kàwé kó sì pọkàn pọ̀ tẹ́lẹ̀, ó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ fún wákàtí méjì gbáko báyìí. Ó máa ń múra gbogbo ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílẹ̀ ṣáájú àkókò, ó sì máa ń yẹ gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wò.”
Ìtẹ̀jáde olójú ewé 32 ni ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, kò sì fẹ̀ ju ìwé ìròyìn yìí lọ. Ó ṣàlàyé ní kedere nípa ète Ọlọ́run fún aráyé ó sì sọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká lè rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. Lára àwọn kókó fífani mọ́ra tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà ni, “Ta Ni Ọlọrun?,” “Ta Ni Jesu Kristi?,” “Kí Ni Ète Ọlọrun fún Ilẹ̀ Ayé?” àti “Kí Ni Ìjọba Ọlọrun?”
Bó o bá fẹ́ láti gba ẹ̀dà kan, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.