ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 3/8 ojú ìwé 32
  • ‘Ó Kún Fún Òtítọ́ Ṣíṣeyebíye’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ó Kún Fún Òtítọ́ Ṣíṣeyebíye’
  • Jí!—2004
Jí!—2004
g04 3/8 ojú ìwé 32

‘Ó Kún Fún Òtítọ́ Ṣíṣeyebíye’

Báyìí ni olùdarí ilé tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tí àìsàn tí ò gbóògùn ń ṣe ní ìlú Illinois, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe ṣàpèjúwe ìwé pẹlẹbẹ náà Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ló fi ìwé pẹlẹbẹ yìí àti ìwé ìròyìn Jí! kan ránṣẹ́ sí i nítorí pé, nígbà tí Ẹlẹ́rìí náà ka ìwé náà, ó rí i pé pípara ẹni wọ́pọ̀ láàárín àwọn àgbàlagbà. Nígbà tí olùdarí yìí gba ìwé yẹn, ojú ẹsẹ̀ ló fèsì.

Lẹ́yìn tí olùdarí yìí rí i pé ìwé Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú yìí kún fún òtítọ́ tó ṣeyebíye, ó kọ̀wé pé: “Inú mi yóò dùn láti mú kí ìwé yìí wà lárọ̀ọ́wọ́tó . . . fún àwọn ìdílé tí yóò rí ìtùnú gbà látinú ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó wà nínú ìwé náà, àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú rẹ̀, àtàwọn ìjíròrò tó wà níbẹ̀.”

Kíá ni Ẹlẹ́rìí náà tẹ olùdarí náà láago, tó sì sọ fún un pé òun á wá rí i lójúkojú. Olùdarí náà sọ pé òun fẹ́ ogún ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, ó sì tún sọ pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí náà máa wá sọ́dọ̀ àwọn lóṣù méjì méjì tàbí lóṣù mẹ́ta mẹ́ta, kí wọ́n sì máa kó ìwé náà dání.

Ó ṣeé ṣe kí ìwọ, tàbí ẹnì kan tó o mọ̀, rí ìtùnú nípa kíka ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí. Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé yìí, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, mo fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́