ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 8/8 ojú ìwé 13-18
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Jí!—2004
Jí!—2004
g04 8/8 ojú ìwé 13-18

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ ó sì rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn níbi tí a tẹ̀ ẹ́ sí lójú ìwé 18. Bí ẹ bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìdáhùn yìí, ẹ wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Láyé àlùfáà àgbà wo ni Sámúẹ́lì di wòlíì? (1 Sámúẹ́lì 3:10-13)

2. Orúkọ wo làwọn ọmọ Ámórì máa ń pe Òkè Hámónì? (Diutarónómì 3:9)

3. Ta ni Ábúráhámù fẹ́ lé Sérà, ọmọkùnrin mélòó ló sì bí fún un? (Jẹ́nẹ́sísì 25:1, 2)

4. Kí ló fà á tí wọn kì í fi wáìnì tuntun sínú àwọn ògbólógbòó àpò awọ? (Lúùkù 5:37)

5. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí idà tí Éhúdù fi pa Ẹ́gílónì, aninilára Ọba Móábù? (Onídàájọ́ 3:16-22)

6. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Jésù ní “Olórí Aṣojú ìyè”? (Ìṣe 3:15; 4:12)

7. Kí ló fà á tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan la lè pè ní ẹni pípé ní gbogbo ọ̀nà? (2 Sámúẹ́lì 22:31; Máàkù 10:18)

8. Ní ti àwọn ẹran tí wọ́n fi ń rúbọ, kí ló fà á tí “gbogbo ọ̀rá [fi] jẹ́ ti Jèhófà”? (Léfítíkù 3:9-16)

9. Ẹyẹ aṣọdẹ lílágbára wo la mọ̀ dunjú fún agbára tó ní láti ríran jìnnà? (Jóòbù 39:27, 29)

10. Orúkọ oyè wo ni Bíbélì lò fún Jèhófà, fún àwọn ohun mìíràn táwọn èèyàn ń sìn, àti fún àwọn ènìyàn? (Ẹ́kísódù 7:1)

11. Wòlíì wo ni Jèhófà lò láti sàsọtẹ́lẹ̀ bí ìjọba Sólómọ́nì á ṣe pín? (1 Àwọn Ọba 11:29-32)

12. Nígbà tí Jésù ń ṣàkàwé bó ṣe fẹ́ láti kó àwọn ọlọ́kàn yíyigbì èèyàn tó wà ní Jerúsálẹ́mù jọ pọ̀, ohun ọ̀sìn wo ni Jésù mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀? (Lúùkù 13:34)

13. Kí ni Jésù pè ní “fìtílà ara”? (Mátíù 6:22)

14. Àkókò wo la sọ fún Dáníẹ́lì pé àwọn èèyàn yóò lóye àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀? (Dáníẹ́lì 12:4)

15. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe bọ́ lọ́wọ́ àwọn Júù tó wà ní Damásíkù tí wọ́n gbìmọ̀ àtipa á? (Ìṣe 9:25)

16. Kí ló ti mú káwọn kan “ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́” tó sì ti mú kí wọ́n ní “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora”? (1 Tímótì 6:10)

17. Níbàámu pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà fún Mósè, àwọn amí mélòó ló rán lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, àwọn wo ló sì mú ìròyìn rere wá? (Númérì 13:2; 14:6-9)

18. Ta ni Késárì tá a mẹ́nu kàn nínú Ìṣe 25:11, tí Pọ́ọ̀lù ké gbàjarè sí pé kí wọ́n gbé ẹjọ́ òun tọ̀ lọ nígbà tó ń jẹ́jọ́ níwájú Fẹ́sítọ́ọ̀sì?

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Élì

2. Sénírì

3. Kétúrà; mẹ́fà

4. Nítorí pé nígbà tí wáìnì náà bá ń díbà, yóò bẹ́ àwọn àpò awọ tó ti gbó náà

5. Ẹ́gílónì sanra bọ̀rọ̀kọ̀tọ̀ bọrọkọtọ débi pé ńṣe ni idà náà wọlé ṣinrá sínú ikùn rẹ̀

6. Nítorí pé “kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn.” Nípasẹ̀ Jésù ni Ọlọ́run pèsè ìràpadà, òun sì ni ó yàn ṣe Onídàájọ́

7. Jèhófà nìkan ni adára-má-kù-síbì-kan, ẹni tó tayọ nínú ọlá ńlá, ẹni tí gbogbo ìyìn yẹ fún àti ẹni táwọn ànímọ́ àti agbára rẹ̀ tayọ

8. Nítorí pé wọ́n ka ọ̀rá sí apá tó dára jù lọ lára ẹran, ọ̀rá yìí ló ń ṣàpẹẹrẹ pé apá tó dára jù lọ la gbọ́dọ̀ fi fún Jèhófà

9. Idì

10. Ọlọ́run

11. Áhíjà

12. Àgbébọ̀ adìẹ

13. Ojú

14. “Àkókò òpin”

15. Lóru, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e sínú apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì gba ojú ihò kan lára ògiri sọ̀ ọ́ kalẹ̀

16. “Ìfẹ́ owó”

17. Méjìlá; Jóṣúà àti Kálébù

18. Nérò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́